Ìyìn: Àṣàrò nínú Orin DáfídìÀpẹrẹ

Worship: A Study in Psalms

Ọjọ́ 1 nínú 106

Kíni ó sọ?

Ọlọ́run ńbukun ni, O sì n dá ààbò bo àwọn olódodo. Ọba Ẹni-àmì-òróró Olúwa ni yíó ṣe àkóso, tí yíó sì ṣe ìdájọ́ ayé. Àwọn olórí tí ní òye ni a bùkún fún tí a sì fún ní ààbò bí wọ́n ti ń sìn tí wọ́n sì n bu ọlá fún Un.

Kíni ó túmọ̀ sí?

Orin Dáfídì èkíní fi ìyàtọ̀ ńláǹlà hàn láàrín olódodo àti ènìyàn búburú. A yànnàná àwọn méjèèjì nípa bí wọ́n ṣe ń lo àkókò wọn àti àbájáde àwọn ìlépa ìgbésí ayé wọn. Oníwà-bíi-Ọlọ́run ṣe àwárí èrèdí ìgbésí-ayé rẹ̀ nípa kíka Ìwé Mímọ́ àti ṣíṣe àṣàrò dípò fífi etí sílẹ̀ sí àwọn orísun ìmọ̀ràn tí kò bá ìfẹ́ Ọlọ́run mu. Bí ojú Olúwa ṣe ńṣe amọ̀nà àwọn tí nṣe Tirẹ̀, ni ẹnití ó kọ Olúwa ti yàn láti gbé láìsí ààbò Rẹ̀. Orin Dáfídì kejì ṣe àfihàn ìbínú Ọmọ Ọlọ́run ní ọ́jọ́ iwájú lóríi àwọn ènìyàn tí ńtẹ̀síwájú nínú kíkọ̀ Ọ́ sílẹ̀. Àwọn tí ó ní ọgbọ́n ni wọ́n rí ààbò nípasẹ̀ Ọmọ, tí wọ́n sìn Ín, dípo kí wọ́n lòdì sí I.

Báwo ni kí ń ṣe dáhùn?

Bí o ṣe ń lo àkókò rẹ ṣe àfihàn ohun púpọ nípa rẹ. Ǹjẹ́ a lè ṣe àpèjúwe àwọn ìlépa rẹ lọ́wọ́lọ́wọ́ bíi ti oníwà-bíi-Ọlọ́run? Ronú nípa bí ìfẹ́ ọkàn rẹ kọ̀ọ̀kan ṣe bẹ̀rẹ̀. Ǹjẹ́ ò ń tẹ̀lé ìtọ́sọ́nà ti Ẹ̀mi Mímọ lẹ́yìn adúra àti ìṣàrò lórí Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run bí? Àbí àwọn tí wọ́n ti kọ àṣẹ Ọlọ́run l'órí ìgbésí ayé wọn ti ní ipá lórí rẹ? Gẹ́gẹ́ bíi ọmọlẹ́hìn Krístì, a fi òdodo Rẹ̀ bò ọ́, èyí fún ọ ní ìgbésí ayé àti ọjọ́ iwájú tí ó yàtọ̀ sí ti àwọn tí ó kọ̀ Ọ́ sílẹ̀. Lónìí, ṣe ìpinnu láti lépa ohun kan tí yíó ṣe àfihàn ìpinnu Ọlọ́run lórí rẹ àti ìtọ́sọ́nà tí Ẹmi Mímọ.

Nípa Ìpèsè yìí

Worship: A Study in Psalms

Àwọn sáàmù jẹ́ àkójọpọ̀ àwọn ewì àti àwọn orin tí a kọ ní ìkọjá ẹgbẹ̀rún ọdún sẹ́yìn. Bí àwọn Sáàmú ṣe ní àwọn ìyìn aláyọ̀ àti àwọn ìbànújẹ́ ọkàn, gbogbo ìwé náà jẹ́rìí sí ìfẹ́ ìdúróṣinṣin ti Ọlọ́run ní sí àwọn ènìyàn Rẹ̀ ní gbogbo ọ̀nà. Gẹ́gẹ́ bí ìwé tí ó wá ní agbedeméjì ìjọsìn Májẹ̀mú Láíláí, sáàmù kọ̀ọ̀kan ní ìrètí láti yọrí sí ìyìn Ọlọ́run nínú ikú àti àjínde Jésù Kristi.

More

Ó wù wá láti dúpẹ lọ́wọ́ ilé ìjọsìn onítẹ̀bọmi L. Camden kejì tí ó wà ní òpópónà Tọ́másì Tommy fún ìpèsè ẹ̀kọ́ yì i. Fún àlàyé ní kíkún sí i. jọ̀wọ́ kàn sí: http://www.trbc.org