Ìyìn: Àṣàrò nínú Orin DáfídìÀpẹrẹ

Kíni o sọ?
Orúkọ Olúwa ní ọlánlú ju èyíkéyìí tí ó wà ní orí ilẹ̀ lọ, tí ìyìn yẹ fún. Bí a bá ṣe àkíyèsí títóbi ẹ̀dá Ọlọrun - kíni ìdí rẹ̀ tí Ó fi ògo, ọlá, àti itọju fún èníyàn?
Kíni o túmọ̀ sí?
Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé kíún ni Dáfídì rí nínú àrágbá yamúyamù àgbáálá ayé wa yìí, ó ní ìmọ̀lára pé òun kò já mọ́ nǹkan kan nígbà tí ó wo ayé tí ó yí i ká tí ó sì ń ṣe àṣàrò nípa Ọlọ́run tí Ó dá gbogbo rẹ̀ ní ẹ̀kúnrẹ́rẹ̀ àti ní pípé pérépéré. Síbẹ̀, Ọlọ́run ẹlẹ́rùjẹ̀jẹ̀ yìí dá àwọn èniyàn, Ó fi wọn jẹ ọba ohun gbogbo tí Ó dá, Ó sì fi iyè sí ìgbésí ayé wọn. Nínú gbogbo ohun alààyè tí Ó dá, èé ṣe tí Ọlọ́run yóò fi fún ọmọ-ènìyàn ní irú àfiyèsí bẹ́ẹ̀? Yàtọ̀ sí àwọn ẹyẹ, ẹja, àti àgùntàn, a dá àwọn ènìyàn ní àwòrán Ọlọ́run. Ọmọ-ènìyàn nìkan ni ó ní ágbára láti ní ìbásepọ̀ pẹ̀lú Olúwa, èyí tí ó fún ni ní ìdí tó láti mọ rírì ògo Rẹ̀ kí a sì yin orúkọ rẹ̀ tí ó dára, tí ó sì ní ọlá ńlá
Báwo ni kí n ṣe dáhùn?
Bí ohunkohun bá ṣe pẹ́ ní ṣàkáánì rẹ tó, ní o kò ṣe níi ní àkàsí rẹ̀ tó. Ní ìbámu pẹ̀lú ibi tí o ń gbé, o lè máa rí àwọn ìrísí òkè ńláńlá tí ó rẹwà, pẹ̀tẹ́lẹ̀ tí ó tẹ́jú, tàbí títẹ́rẹrẹ òkun bí ó ṣe fi ẹnu kò sánmọ̀. Ṣùgbọ́n ìgbà wó ní o ti dúró làti ronú lóri ohun tí o rí? Ṣe ètò láàrin ọ̀sẹ̀ yìí láti gun òkè kan, wo oòrùn bí ó ṣe n jáde tí ó sì ń wọlé, tàbí wo àwọn ìràwọ̀. Ní ìgbà tí o bá dé òpin ìrìn-àjò rẹ, ka Sáàmù 8 gẹ́gẹ́ bí iṣẹ́ ìsìn. Ó ṣeé ṣe kí o fi ibẹ̀ sílẹ̀ pẹ̀lú ìmọ̀lára àgbààyanu tuntun àti ìmọrírì tuntun fún àjọṣepọ̀ rẹ pẹ̀lú Ọlọ́run wa ẹlẹ́rù ní ìyìn
Ìwé mímọ́
Nípa Ìpèsè yìí

Àwọn sáàmù jẹ́ àkójọpọ̀ àwọn ewì àti àwọn orin tí a kọ ní ìkọjá ẹgbẹ̀rún ọdún sẹ́yìn. Bí àwọn Sáàmú ṣe ní àwọn ìyìn aláyọ̀ àti àwọn ìbànújẹ́ ọkàn, gbogbo ìwé náà jẹ́rìí sí ìfẹ́ ìdúróṣinṣin ti Ọlọ́run ní sí àwọn ènìyàn Rẹ̀ ní gbogbo ọ̀nà. Gẹ́gẹ́ bí ìwé tí ó wá ní agbedeméjì ìjọsìn Májẹ̀mú Láíláí, sáàmù kọ̀ọ̀kan ní ìrètí láti yọrí sí ìyìn Ọlọ́run nínú ikú àti àjínde Jésù Kristi.
More