Ìyìn: Àṣàrò nínú Orin DáfídìÀpẹrẹ

Worship: A Study in Psalms

Ọjọ́ 7 nínú 106

Kíni ó sọ?

Orin ayọ̀ Dáfídì yin Olúwa gẹ́gẹ́ bíi Onídàájọ́ òdodo fún àwọn ènìyàn búburú.

Kíni ó túnmọ̀ sí?

Dáfídì láti inú ìrírí rẹ̀ sọ nípa Olúwa gẹ́gẹ́ bí ẹnití Ó ṣe fi ọkàn tán. Ọ̀dọ̀ Rẹ̀ ni ó ṣeé sá sí nígbàtí ìṣòro bá dé; a kò já àwọn tí wọ́n pe orúkọ Rẹ̀ kulẹ̀. Láti inú ìwòye yìí, Dáfídì nípa àsọtẹ́lẹ̀ kọ nípa ọjọ́ kan tí Ísírẹ́lì yíò ṣẹ́gun gbogbo àwọn ọ̀tá. Ọlọ́run yíò ṣe òdodo nítorí àwọn ènìyàn Rẹ̀ gẹ́gẹ́ bí Ó ti ṣe fún Dáfídì fúnra rẹ̀. Lẹ́yìn náà ni ó ṣe àṣàrò ní orí ìgbésí ayé rẹ̀ lọ́wọ́lọ́wọ́ níbití ó ti níílò àánú Ọlọ́run. Dáfídì yin Olúwa ó sì bẹ̀ Ẹ́ fún ìrànlọ́wọ́ lẹ́ẹ̀kan náà, ó ní, “Má ṣe dúró nísinsìnyí, Olúwa!” Ìdí ẹ̀bẹ̀ Dáfídì yìí fi hàn wá ìdí tí ó fi jẹ́ “ẹni-bí-ọkàn-Ọlọ́run” – ó pòǹgbẹ láti yin Ọlọ́run ní gbangba ní Síónì.

Báwo ni kí n ṣe dáhùn?

Àwọn ènìyàn mííràn dẹ́kun wíwá sí ilé ìjọsìn nítorí Ọlọ́run kò dáhùn àdúrà wọn ní ọ̀nà tí ó bá ìfẹ́ wọn mu ní ìgbà kan rí, wọ́n sì gbà pé kò ṣe ti àwọn. Ṣé inú rẹ kò dùn sí bí Ọlọ́run ṣe b'ójú tó ọ̀rọ̀ kan pàtó? Ó lè máà gbìyànjú láti fún ọ ní ǹǹkan tí ó tóbi ju ìdẹ̀rùn ẹsẹ̀kẹsẹ̀ – òye ìwàláàyè Rẹ̀ tímọ́tímọ́. Ìṣòro kò lè ṣàì má wà ní aye yìí, ṣùgbọ́n Olúwa ni ààbò wa tí ó ṣeé gbẹ́kẹ̀ lé. Bí ó ti wù kí ó rí, òtítọ́ àti òdodo ni ìdáhùn Rẹ̀. Sọ fún ẹnìkan lónìí ohun tí Ọlọ́run ti ṣe fún ọ s'ẹ́yìn, bí o bá tilẹ̀ ṣì ń gbàdúrà nípa ipò kan tí ó nira.

Ìwé mímọ́

Nípa Ìpèsè yìí

Worship: A Study in Psalms

Àwọn sáàmù jẹ́ àkójọpọ̀ àwọn ewì àti àwọn orin tí a kọ ní ìkọjá ẹgbẹ̀rún ọdún sẹ́yìn. Bí àwọn Sáàmú ṣe ní àwọn ìyìn aláyọ̀ àti àwọn ìbànújẹ́ ọkàn, gbogbo ìwé náà jẹ́rìí sí ìfẹ́ ìdúróṣinṣin ti Ọlọ́run ní sí àwọn ènìyàn Rẹ̀ ní gbogbo ọ̀nà. Gẹ́gẹ́ bí ìwé tí ó wá ní agbedeméjì ìjọsìn Májẹ̀mú Láíláí, sáàmù kọ̀ọ̀kan ní ìrètí láti yọrí sí ìyìn Ọlọ́run nínú ikú àti àjínde Jésù Kristi.

More

Ó wù wá láti dúpẹ lọ́wọ́ ilé ìjọsìn onítẹ̀bọmi L. Camden kejì tí ó wà ní òpópónà Tọ́másì Tommy fún ìpèsè ẹ̀kọ́ yì i. Fún àlàyé ní kíkún sí i. jọ̀wọ́ kàn sí: http://www.trbc.org