IBUKÚN ni fun ọkunrin na ti kò rìn ni ìmọ awọn enia buburu, ti kò duro li ọ̀na awọn ẹlẹṣẹ, ati ti kò si joko ni ibujoko awọn ẹlẹgàn. Ṣugbọn didùn-inu rẹ̀ wà li ofin Oluwa; ati ninu ofin rẹ̀ li o nṣe aṣaro li ọsan ati li oru. Yio si dabi igi ti a gbìn si eti ipa odò, ti nso eso rẹ̀ jade li akokò rẹ̀; ewe rẹ̀ kì yio si rẹ̀; ati ohunkohun ti o ṣe ni yio ma ṣe dede. Awọn enia buburu kò ri bẹ̃: ṣugbọn nwọn dabi iyangbo ti afẹfẹ nfẹ lọ. Nitorina awọn enia buburu kì yio dide duro ni idajọ, bẹ̃li awọn ẹlẹṣẹ kì yio le duro li awujọ awọn olododo. Nitori Oluwa mọ̀ ọ̀na awọn olododo: ṣugbọn ọ̀na awọn enia buburu ni yio ṣegbe.
Kà O. Daf 1
Feti si O. Daf 1
Pín
Fi gbogbo Èyá wéra: O. Daf 1:1-6
7 Awọn ọjọ
Bibeli ṣapejuwe ibukun ọkunrin naa ti o yipada kuro ninu imọran awọn alaiwa-bi-Ọlọrun, ti o kọ̀ lati rin ni ọna awọn ẹlẹṣẹ, ti o si kọ̀ lati darapọ mọ ẹgan wọn. Ó ṣàpèjúwe àbájáde ìkẹyìn àwọn tí inú wọn dùn sí òfin Ọlọ́run àti bí ọ̀nà àwọn ẹlẹ́ṣẹ̀ ṣe ṣègbé. Ìfọkànsìn yìí ní lọ́kàn láti tú ìsọfúnni tó wà nínú ẹsẹ mẹ́ta àkọ́kọ́ ní orí ìbẹ̀rẹ̀ ìwé Sáàmù.
Ṣe àfipamọ́ àwọn ẹsẹ, kàá ní aìsìní orí ayélujára, wo àwọn àgékúrú ìkọ́ni, àti díẹ̀ síi!
Ilé
Bíbélì
Àwon ètò
Àwon Fídíò