Ìyìn: Àṣàrò nínú Orin DáfídìÀpẹrẹ

Kínni ó sọ?
Onísáàmù ń ké sí ohun gbogbo tí ó ní èémí láti kọrin ìyìn sí Olúwa fún ìṣẹ̀dá Rẹ̀, ìyọ́nú Rẹ̀, àwọn iṣẹ́ agbára Rẹ̀, àti títóbi gíga jùlọ.
Kínni ìtúmọ̀ rẹ̀?
Ẹ ò rí i pé ìparí àgbàyanu lèyí jẹ́ sí eré orin ìyìn àti àdúrà ti Ìwé Mímọ́! Ìwé Orin Dáfídì àkọ́kọ́ bẹ̀rẹ̀ pẹ̀lú ìbùkún Ọlọ́run lórí ọkùnrin tí ó nṣe àṣàrò lori Ọrọ Rẹ. Ìwé Orin Dáfídì tí o kẹ́yìn parí pẹ̀lú ènìyàn àti “ohun gbogbo tí ó ní ẹ̀mí,” tí o yin Olúwa. Nígbà míì, yíyin Ọlọ́run lè dákẹ́ jẹ́ẹ́ ká sì máa ronú jinlẹ̀. Bí ó ti wù kí ó rí, àwọn Ìwé Orin Dáfídì mẹ́ta tí ó gbẹ̀yìn ké sí gbogbo ìṣẹ̀dá láti dara pọ̀ mọ́ iṣẹ́ ìsìn kan láti yin Ẹlẹ́dàá wọn. Àwọn tí ó mọ Ọlọ́run ní ìdí pàtàkì kan láti kọ orin titun ti ìyìn sí Olúwa - orin ìgbàlà. Òun ni ẹni tí ó ti fọ ẹ̀ṣẹ̀ wọn nù, ó sì ti fìyà jẹ àwọn ọ̀tá wọn. Ó tọ́ láti yin Ọlọ́run ní ibi gbogbo, ní gbogbo ipò, àti pẹ̀lú gbogbo ẹ̀mí
Báwo ni kí n ṣe dáhùn?
Báwo ni o ṣe bẹ̀rẹ̀ àti parí ọjọ́ rẹ? Ǹjẹ́ o jí pẹ̀lú ìbẹ̀rùbojo bí o ṣe ń ronú nípa àwọn ìṣẹ̀lẹ̀ ọjọ́ náà, tàbí o rántí pé, “Èyí ni ọjọ́ tí Olúwa dá—ẹ jẹ́ kí a yọ̀, kí a sì máa yọ̀ nínú rẹ̀”? Ọlọ́run fẹ́ràn láti gbọ́ ìyìn rẹ̀ bí o ṣe ń péjọ pẹ̀lú àwọn ẹlòmíràn láti jọ́sìn, ṣùgbọ́n Ó tún máa ń rí ìdùnnú ńlá nígbà tí ìyìn rẹ bá bá àwọn àṣàyàn rẹ̀ mu àti ọ̀nà tí o ń gbé. Gbìyànjú láti mú ọjọ́ rẹ sí àwọn ètò ti àwọn orin Dáfídì. Bẹ̀rẹ̀ ọjọ́ náà láti rò lórí ọgbọ́n Ọlọ́run nínú Ìwé Mímọ́; Jẹ́ kí àwọn ìṣe sí rẹ ní jákèjádò ọjọ́ Jẹ́ ìfihàn ti bí o ṣe ń ifẹ Rẹ̀, kí o sì parí ọjọ́ náà fífi í mọrírì fún ẹni tí Ọlọ́run Jẹ́ àti dúpẹ́ fún ohun tí Ó ṣe. Ṣé ìwọ yóò dára pọ̀ mọ́ gbogbo ẹ̀dá láti iyin Olúwa fún títóbi Rẹ̀? Ṣé ìwọ yóò dúpẹ́ lọ́wọ́ Rẹ̀ ní báyìí fún ìpèsè fún ìgbàlà rẹ? Pinnu láti yin Olúwa ní ipò kí pò tí o kọjú pẹ̀lú gbogbo ẹ̀mí títí di ọjọ́ ikú rẹ. Yóò fún ọ ní okun nípa ti ara, ní ti ìmọ̀lára, àti nípa tẹ̀mí.
Nípa Ìpèsè yìí

Àwọn sáàmù jẹ́ àkójọpọ̀ àwọn ewì àti àwọn orin tí a kọ ní ìkọjá ẹgbẹ̀rún ọdún sẹ́yìn. Bí àwọn Sáàmú ṣe ní àwọn ìyìn aláyọ̀ àti àwọn ìbànújẹ́ ọkàn, gbogbo ìwé náà jẹ́rìí sí ìfẹ́ ìdúróṣinṣin ti Ọlọ́run ní sí àwọn ènìyàn Rẹ̀ ní gbogbo ọ̀nà. Gẹ́gẹ́ bí ìwé tí ó wá ní agbedeméjì ìjọsìn Májẹ̀mú Láíláí, sáàmù kọ̀ọ̀kan ní ìrètí láti yọrí sí ìyìn Ọlọ́run nínú ikú àti àjínde Jésù Kristi.
More