Ìyìn: Àṣàrò nínú Orin DáfídìÀpẹrẹ

Kíni ó sọ?
Dáfídì gbẹ́kẹ̀lé Ọlọ́run bíi olùdáǹdè rẹ̀, bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé ọ̀pọ̀lọpọ̀ ọ̀tá lépa rẹ̀. Ó wo Olúwa, tí í ṣe aláàánú àti olódodo, ó sì sùn ní àlàáfíà.
Kíni ìtumọ̀ rẹ̀?
Dáfídì sá lọ kúrò ní ọ́dọ̀ Ábúsálómù ọmọkùnrin rẹ̀ alárèkérekè ẹni tí kì í ṣe kìkì pé ó jí ìtẹ́ bàbá rẹ̀ nìkan, ṣùgbọ́n ó tún gbìyànjú láti fi òpin sí ẹ̀mí rẹ̀. Láàárín ipò àìnírètí, ọkàn Dáfídì wà ní àlàáfíà tó láti sùn dáadáa. Báwo ní èyí ṣe ṣẹlẹ̀? Ó mọ̀ pé òun dúró ní ìhà ti Ọlọ́run, ó sì ní ìgbẹkẹ̀lé nínú agbára Ọlọ́run pé yío dá òun ní ìdè. Bí ó ṣe dùbúlẹ̀ ní òru náà, Dáfídì gba àdúrà fún ìtura, ó d'ojúkọ ohun tí ó mọ̀ pé ó jẹ́ òtítọ́ — Ọlọ́run olódodo àti aláàánú rẹ̀ ń fi etí sí àwọn ènìyàn Rẹ̀, ó sì ń dáàbò bò wọ́n. Àsìkò ìpòrurù ọkàn nínú ìgbésí ayé ọba di àsìkò láti ní ìrírí ìmúdúró nínú Olúwa rẹ̀.
Báwo ni kí n ṣe dáhùn?
Àìbalẹ̀ ọkàn àti àìní ìrètí lè ná ọ ní ìsinmi tí o níìlò. Nígbàtí o kò bá rí oorun sùn ní àárín ògànjọ́, o lè máa ronú ohun tí ó gba oorun ní ojú rẹ tàbí kí ọ bẹ̀rẹ̀ síí bá Ẹni tí ó mọ̀ ọ́ tí ó sì mọ ìṣòro náà tinu-tòde. Sọ bí nǹkan ṣe rí ní ára rẹ fún Ọlọ́run, wá àwọn ìdí láti fi ìmoore hàn, kí o sì yìn Ín fún àwọn àbúdà Rẹ̀ tí ó bá ipò náà mú. Lẹ́hìn náà tú àníyàn rẹ palẹ̀ fún Un kí o sì fi tinútinú gbà bí Ó ṣe ń ṣiṣẹ́. Àlááfíà Ọlọ́run kì í ṣe àbájáde ipòkípò ṣùgbọ́n àbájáde ìgbẹ́kẹ̀lé aláìlẹ́gbẹ́ nínú àbùdà Rẹ̀(Fílí 4:6-8).
Ìwé mímọ́
Nípa Ìpèsè yìí

Àwọn sáàmù jẹ́ àkójọpọ̀ àwọn ewì àti àwọn orin tí a kọ ní ìkọjá ẹgbẹ̀rún ọdún sẹ́yìn. Bí àwọn Sáàmú ṣe ní àwọn ìyìn aláyọ̀ àti àwọn ìbànújẹ́ ọkàn, gbogbo ìwé náà jẹ́rìí sí ìfẹ́ ìdúróṣinṣin ti Ọlọ́run ní sí àwọn ènìyàn Rẹ̀ ní gbogbo ọ̀nà. Gẹ́gẹ́ bí ìwé tí ó wá ní agbedeméjì ìjọsìn Májẹ̀mú Láíláí, sáàmù kọ̀ọ̀kan ní ìrètí láti yọrí sí ìyìn Ọlọ́run nínú ikú àti àjínde Jésù Kristi.
More