Ìyìn: Àṣàrò nínú Orin DáfídìÀpẹrẹ

Worship: A Study in Psalms

Ọjọ́ 5 nínú 106

>Kí ni ó sọ?

Dáfídì ké pe Ọlọ́run pé kí ó yẹ ọkàn àti èrò inú òun wò – àti ti ọ̀tá rẹ̀ pẹ̀lú – lẹ́yìn náà kí ó ṣe ìdájọ́ òdodo. Ó fi ọpẹ́ àti ìyìn fún Olúwa Ọ̀gá-ògo jùlọ.

Kí ni ó túmọ̀ sí?

Dafidi kọ Sáàmù yìí gẹ́gẹ́ bí èsì sí ọ̀rọ̀ kan tí ará Bẹ́ńjámìnì kan tí ń jẹ́ Kúṣì sọ nípa rẹ̀. Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé a kò kọọ́ sílẹ̀ bẹ́ẹ̀, ó ṣeé ṣe kí Kúṣì jẹ́ ọ̀kan nínú àwọn tí ó wà ní ààfin Sọ́ọ̀lù tí ó ti ń fi irọ́ pípa kún ọkàn ọba nípa Dáfídì (Sámúẹ́lì kini 24:9). Níwọ̀n bí ó ti jẹ́ pé kò sí ohun tí ó fi ara pamọ́ fún Ọlọ́run, Dáfídì sọ fún Un pé kó sọ ohun tó wà ní ọkàn ẹnì kọ̀ọ̀kan, kó sì ṣí òtítọ́ p'ayá. Ó gbẹ́kẹ̀lé Ọlọ́run gẹ́gẹ́ bí Alákòso òdodo àti Onídàájọ́ gbogbo ènìyàn pẹ̀lú. Èyíkéyì ìgbésẹ̀ tí Ó pinnu láti gbé tàbí èyí tí kò ní gbé yóò jẹ òdodo. Ó fi í sílẹ̀ fún Ọlọ́run, ẹni tí ń ṣe òdodo sí gbogbo ènìyàn.

Báwo ni kí n ṣe dáhùn?

Ó ṣeé ṣe pé o ní láti kojú àwọn ènìyàn tí ó níra níwọn ìgbà tí o bá wà láàyè. Báwo ni ó ṣe lè ṣe àfiwé àwọn ìdáhùn rẹ sí irú àwọn ènìyàn yìí pẹ̀lú àwọn ohun tí Dáfídì sọ nínú àyọkà tí òní? Bí ẹ̀sùn kan bá ti wáyé, fi ìrẹ̀lẹ̀ bèèrè lọ́wọ́ Ọlọ́run pé kó fihàn ọ́ bóyá apá kan nínú rẹ̀ dá lé orí òtítọ́. Bèèrè lọ́wọ́ Rẹ̀ láti ṣe àwárí ọkàn àti èrò inú rẹ dé ibi tí ó ṣókùnkùn sì ọ, lẹhìnnà fi sílẹ fún Ọlọrun. Ìyẹn kò túmọ sí pé o kò ní gba àdúrà nípa rẹ̀ mọ, ṣùgbọ́n àwọn àdúrà rẹ yẹ kí o ṣe àfihàn ìjẹ́wọ́ ìrẹ̀lẹ̀ irú ẹni tí Ọlọ́run jẹ́ - Olúwa Ọ̀gá-ògo jùlọ, Onídàjọ́ òdodo. Ohunkóhun tí Ó bá pinnu jẹ́ òótọ́. Irú ipò tàbí ìbásepọ̀ wo ni o níílò láti gbàdúrà nípa rẹ̀ báyí kí o sì fi sílẹ̀ ní ọwọ́ Ọlọ́run olódodo?

Ìwé mímọ́

Nípa Ìpèsè yìí

Worship: A Study in Psalms

Àwọn sáàmù jẹ́ àkójọpọ̀ àwọn ewì àti àwọn orin tí a kọ ní ìkọjá ẹgbẹ̀rún ọdún sẹ́yìn. Bí àwọn Sáàmú ṣe ní àwọn ìyìn aláyọ̀ àti àwọn ìbànújẹ́ ọkàn, gbogbo ìwé náà jẹ́rìí sí ìfẹ́ ìdúróṣinṣin ti Ọlọ́run ní sí àwọn ènìyàn Rẹ̀ ní gbogbo ọ̀nà. Gẹ́gẹ́ bí ìwé tí ó wá ní agbedeméjì ìjọsìn Májẹ̀mú Láíláí, sáàmù kọ̀ọ̀kan ní ìrètí láti yọrí sí ìyìn Ọlọ́run nínú ikú àti àjínde Jésù Kristi.

More

Ó wù wá láti dúpẹ lọ́wọ́ ilé ìjọsìn onítẹ̀bọmi L. Camden kejì tí ó wà ní òpópónà Tọ́másì Tommy fún ìpèsè ẹ̀kọ́ yì i. Fún àlàyé ní kíkún sí i. jọ̀wọ́ kàn sí: http://www.trbc.org