Ìyìn: Àṣàrò nínú Orin DáfídìÀpẹrẹ

Worship: A Study in Psalms

Ọjọ́ 9 nínú 106

Kini o sọ?

Dáfídì sá di Olúwa, ẹni tó ń ṣàkóso lọ́nà tó tọ́ àti òdodo láti orí ìtẹ́ Rẹ̀ ọ̀run.

Kini o túmọ̀ sí?

Nígbà tí Dáfídì ń sìn ní ààfin Sọ́ọ̀lù Ọba, ó kọ Sáàmù yìí lẹ́yìn tí ó ti pa Gòláyátì. Nítorí owú àti ìlara, Sọ́ọ̀lù gbìyànjú láti pa Dáfídì lọ́pọ̀ ìgbà ní àwọn ọdún wọ̀nyẹn. Gbogbo wọn sì fún Dáfídì ní ìmọ̀ràn kan náà pé, “Sáré!” Bó tilẹ̀ jẹ́ pé ọ̀ràn náà le koko, Dáfídì wà ni ibi gan-an tí Ọlọ́run fẹ́ kí ó wà. Ìbá ti jẹ́ àìgbọràn sí Ọlọ́run fún Dáfídì láti sá lọ. Dípò bẹ́ẹ̀, ó fi ẹ̀mí rẹ̀ lé Ọlọ́run lọ́wọ́. Ó yàn láti fọkàn tán Olúwa gẹ́gẹ́ bí ó ti máa ń ṣe nígbà gbogbo. Nítorí pé Dáfídì yàn láti gbé ní ọ̀nà tí ó tọ́, Ọlọ́run olódodo rẹ̀ dúró tì ì.

Bawo ni o ṣe yẹ ki ń dáhùn?

Kini o jẹ ki o fẹ lati dawọ silẹ? Njẹ awọn nkan ti bẹrẹ si buru si ni ibi iṣẹ rẹ tabi ninu ile ijọsin rẹ bi? Ṣé awọn ọrẹ gba ọ niyanju lati jade ṣaaju ki awọn nkan to buru ré kọjá? O jẹ dandan lati lọ kuro ni kiakia lati ohunkohun ti o fa idamu tabi irẹwẹsi. Bí ó ti wù kí ó rí, nígbà mìíràn, Ọlọ́run lè pè ènìyàn láti kojú àwọn ipò tí ó tayọ òye ènìyàn. Idi kan ṣoṣo ni o wa fun ọmọ Ọlọrun lati yi itọsọna pada – èyí yí sì ni igbọràn si Ọlọrun. Bákan náà, ìdí àkọ́kọ́ tí àwọn Kristẹni fi dúró sí ibi tí wọ́n wà ni ìmọ̀ pé Ọlọ́run ti fi wọ́n síbẹ̀, kò sì tíì dá wọn sílẹ̀ láti lọ. Èyíkéyìí tí ibà jẹ́, ṣe iwọ yoo gbẹkẹle Ọlọrun tó bẹ́y lati fi itọsọna igbesi aye rẹ si ọwọ Rẹ? Kí ló ń darí rẹ láti ṣe lónìí?

Ìwé mímọ́

Nípa Ìpèsè yìí

Worship: A Study in Psalms

Àwọn sáàmù jẹ́ àkójọpọ̀ àwọn ewì àti àwọn orin tí a kọ ní ìkọjá ẹgbẹ̀rún ọdún sẹ́yìn. Bí àwọn Sáàmú ṣe ní àwọn ìyìn aláyọ̀ àti àwọn ìbànújẹ́ ọkàn, gbogbo ìwé náà jẹ́rìí sí ìfẹ́ ìdúróṣinṣin ti Ọlọ́run ní sí àwọn ènìyàn Rẹ̀ ní gbogbo ọ̀nà. Gẹ́gẹ́ bí ìwé tí ó wá ní agbedeméjì ìjọsìn Májẹ̀mú Láíláí, sáàmù kọ̀ọ̀kan ní ìrètí láti yọrí sí ìyìn Ọlọ́run nínú ikú àti àjínde Jésù Kristi.

More

Ó wù wá láti dúpẹ lọ́wọ́ ilé ìjọsìn onítẹ̀bọmi L. Camden kejì tí ó wà ní òpópónà Tọ́másì Tommy fún ìpèsè ẹ̀kọ́ yì i. Fún àlàyé ní kíkún sí i. jọ̀wọ́ kàn sí: http://www.trbc.org