Ìyìn: Àṣàrò nínú Orin DáfídìÀpẹrẹ

Worship: A Study in Psalms

Ọjọ́ 3 nínú 106

Kí ni ó sọ?

Dáfídì fi Ọlọ́run ṣe ibi ààbò rẹ̀, ó ń retí pé kí Ó dáhùn àwọn àdúrà rẹ̀.

Kí ni ó túmọ̀ sí?

Nígbàtí Dáfídì kọ Sáàmù yìí, ó ń sá pamọ́ fún Sọ́ọ̀lù, ẹnití ó rò wípé Dáfídì fẹ́ gba ìtẹ́ òun. Lójoojúmọ́, Dáfídì bèèrè fún ìrànlọ́wọ́, ó fi ojú sun àbùdá Ọlọ́run láì yẹ ẹsẹ̀, ó sì ń retí ìdáǹdè Rẹ̀. Ó kọ́ nípa Ọlọ́run nínú àwọn ìdààmú tí ó là kọjá ju bí ó ṣe lè kọ́ ní àwọn ọ̀nà míràn lọ. Ṣíṣẹ́pá-ṣẹ́sẹ̀ tí Dáfídì ṣẹ́pá-ṣẹ́sẹ̀ fún títóbi àtí àsìkò Ọlọ́run ti di ìwà bárakú fún-un. Nínú àsìkò yìí, ìmọ̀ rẹ̀ àti ìgbẹ́kẹ̀lé rẹ̀ nínú Ọlọ́run gbòòrò, ìrírí yìí sọ ọ́ di ẹni tí ó di ọba ilẹ̀ Ísírẹ́lí tí ó ní agbára jùlọ tí àwọn ènìyàn sì tún fẹ́ràn jùlọ.

Báwo ni kí n ṣe dáhùn?

Ọlọ́run mọ gbogbo ìṣòro tí ò dojúkọ. Síbẹ̀ náà, ó ṣe pàtàkì láti mú àwọn ìṣòro yìí lọ sí iwájú Rẹ̀ nínú àdúrà nítorí á máa jẹ́ kí ìgbàgbọ́ àti ìgbẹ́kẹ̀lé rẹ gbòòrò síi. O lè ní láti dojú kọ ìfẹ́ láti ṣe àwọn nkan ní àdábọwọ́ ara-ẹni nígbàtí o bá ń retí, ṣùgbọ́n ìwà láti máa dá nkan ṣe yìí kò gbọdọ̀ rí ààyè nínú ìgbésí ayé onígbàgbọ́. Dípò bẹ́ẹ̀, yàn láti fi gbẹ́kẹ̀lé rẹ sí ìnu àbùdá Ẹni tí o ti fi ìgbàgbọ́ rẹ lé lọ́wọ́. Ọlọ́run yíò bùkún, dá ààbò bó, yíò si fi ojú rere han àwọn ọmọ Rẹ̀, bí ó tilẹ̀ jẹ́ pẹ́ o lè máà rí bí a ṣe fé kí ó rí. Gẹ́gẹ́ bíi Dáfídì, Ọlọ́run lè máa lo àkókò ìrètí yìí láti ṣe ohun kan nínú ọkàn àti ìwà Rẹ̀ tí kò lè sẹlẹ̀ ní ònà míràn.

Ìwé mímọ́

Nípa Ìpèsè yìí

Worship: A Study in Psalms

Àwọn sáàmù jẹ́ àkójọpọ̀ àwọn ewì àti àwọn orin tí a kọ ní ìkọjá ẹgbẹ̀rún ọdún sẹ́yìn. Bí àwọn Sáàmú ṣe ní àwọn ìyìn aláyọ̀ àti àwọn ìbànújẹ́ ọkàn, gbogbo ìwé náà jẹ́rìí sí ìfẹ́ ìdúróṣinṣin ti Ọlọ́run ní sí àwọn ènìyàn Rẹ̀ ní gbogbo ọ̀nà. Gẹ́gẹ́ bí ìwé tí ó wá ní agbedeméjì ìjọsìn Májẹ̀mú Láíláí, sáàmù kọ̀ọ̀kan ní ìrètí láti yọrí sí ìyìn Ọlọ́run nínú ikú àti àjínde Jésù Kristi.

More

Ó wù wá láti dúpẹ lọ́wọ́ ilé ìjọsìn onítẹ̀bọmi L. Camden kejì tí ó wà ní òpópónà Tọ́másì Tommy fún ìpèsè ẹ̀kọ́ yì i. Fún àlàyé ní kíkún sí i. jọ̀wọ́ kàn sí: http://www.trbc.org