Ìyìn: Àṣàrò nínú Orin DáfídìÀpẹrẹ

Worship: A Study in Psalms

Ọjọ́ 4 nínú 106

Kíni ó sọ?

Lẹ́yìn tí Dáfídì ti sunkún ní gbogbo òru, ó bẹ Ọlọ́run pé kí Ó gba ara àti ọkàn òun l'ọ́wọ́ ídè ní ọ̀nà àánú. Ọlọ́run gbọ́ igbe Dáfídì fún ìrànlọ́wọ́.

Kíni ó túmọ̀ sí?

Sáàmù onírònúpìwàdà àkọ́kọ́ fi ìrora tí ó wà nínú rẹ̀ hàn nígbà tí ẹ̀kúnrẹ́rẹ́ ìwúwo ẹ̀ṣẹ̀ bá di mímọ̀ nípasẹ̀ ìdánilójú ti Ẹ̀mí Mímọ́. Ẹ̀ṣẹ̀ náà gan-an ni a kò dárúkọ nínú Sáàmù tí kò ní ìgbà tí a kọ́ yìí, ṣùgbọ́n a sáábà máa ń rò pé ó jẹ́ pípa Ùráyà lẹ́yìn tí Dáfídì ṣe panṣágà pẹ̀lú Bátíṣébà. Ọ̀rọ̀ Dáfídì fi hàn pé Ọlọ́run yọ̀ǹda fún un láti ṣe àìsàn tí ó le koko kí ó tó ronúpìwàdà. Ní àkókò kan náà, àwọn ọ̀tá ń gbìyànjú láti pa á. Ìrora ti ara àti ti ọpọlọ pọ̀ débi pé Dáfídì sunkún ní gbogbo òru débi pé kò lè ríran dáadáa. Ó wù ú láti júbà Ọlọ́run pẹ̀lú ẹ̀rí ọkàn tí ó mọ́, kó sì mú kí àjọṣe òun pẹ̀lú Rẹ̀ padà bọ̀ sí ipò. Àánú Ọlọ́run nìkan ni ìdánilójú ti Dáfídì ní pé Ọlọ́run yíò dáhùn àdúrà rẹ̀ yíò sì fi irú ìdálẹ́jọ́ kan náà sí orí àwọn ọ̀tá rẹ̀.

Báwo ni kí n ṣe dáhùn?

Ní ọ̀pọ̀lọpọ̀ ìgbà, a má ń kùnà láti mọ ìwúwo ẹ̀ṣẹ̀ wa ní kíkún. O lè jọ bí ìgbà tí wọ́n bá fi abẹ́rẹ́ gún ni dípò kí ó jọ ojú ọgbẹ́ jínjìn nínú ẹ̀mí wa. Ó yá wa lára láti sun ẹkùn ní orí àwọn àbájáde ẹ̀ṣẹ̀ ju ipa rẹ̀ ní orí ìdàpọ̀ àtìgbà-de-gbà wa pẹ̀lú Krístì. Bóyá a kì í sáábà ní ìmọ̀lára ìrora tí a ṣe àpèjúwe rẹ̀ nínú Sáàmù yìí nítorí pé a kò ní àjọṣe tímọ́tímọ́ pẹ̀lú Olúwa láti ìbẹ̀rẹ̀. È̩ṣẹ̀ wo ló wà ní ìgbésí ayé rẹ lọ́wọ́lọ́wọ́ tí ó ń ba Ọlọ́run ní ọkàn jẹ́? Má mú ẹ̀ṣẹ̀ ná ní yẹpẹrẹ; dójú kọ ọ́ ní báyìí. Gba agbára ìdálẹ́jọ́ ti È̩mí Mímọ́ láàyè láti fi àánú jẹ́ ojú-ọna rẹ padà sí ìbátan tí ó dára pẹ̀lú Krístì. Ṣé ìwọ yíòo Orin Dáfídì orí kẹfà gẹ́gẹ́ bíi àdúrà tìrẹ ni ónì bí?

Ìwé mímọ́

Nípa Ìpèsè yìí

Worship: A Study in Psalms

Àwọn sáàmù jẹ́ àkójọpọ̀ àwọn ewì àti àwọn orin tí a kọ ní ìkọjá ẹgbẹ̀rún ọdún sẹ́yìn. Bí àwọn Sáàmú ṣe ní àwọn ìyìn aláyọ̀ àti àwọn ìbànújẹ́ ọkàn, gbogbo ìwé náà jẹ́rìí sí ìfẹ́ ìdúróṣinṣin ti Ọlọ́run ní sí àwọn ènìyàn Rẹ̀ ní gbogbo ọ̀nà. Gẹ́gẹ́ bí ìwé tí ó wá ní agbedeméjì ìjọsìn Májẹ̀mú Láíláí, sáàmù kọ̀ọ̀kan ní ìrètí láti yọrí sí ìyìn Ọlọ́run nínú ikú àti àjínde Jésù Kristi.

More

Ó wù wá láti dúpẹ lọ́wọ́ ilé ìjọsìn onítẹ̀bọmi L. Camden kejì tí ó wà ní òpópónà Tọ́másì Tommy fún ìpèsè ẹ̀kọ́ yì i. Fún àlàyé ní kíkún sí i. jọ̀wọ́ kàn sí: http://www.trbc.org