Ìyìn: Àṣàrò nínú Orin DáfídìÀpẹrẹ

Worship: A Study in Psalms

Ọjọ́ 8 nínú 106

Kíni ó sọ?

Ó dàbí ẹnipé Olúwa jìnnà sí ètekéte àwọn ènìyàn búburú. Ṣùgbọ́n ó lè pè wọ́n sí àkíyèsí àṣìṣe wọn, kí ó sì gbèjà àwọn tí a ni lára ​​tí wọ́n dúró de Òun fún ìrànlọ́wọ́.

Kíni ó túmọ̀ sí?

Ó hàn sí onísáàmù náà pé Ọlọ́run ń fi ara Rẹ̀ pamọ́ nígbà tí áwọn ènìyàn búburú ń gbìmọ̀ pọ̀ lòdì sí àwọn aláìṣẹ̀ àti aláìlera. Ìgbéraga ló sún àwọn aláìṣèfẹ́ Ọlọ́run wọ̀nyí láti lo ègún, irọ́, àti ìhalẹ̀mọ́ni láti tako Ọlọ́run àti àwọn ènìyàn Rẹ̀. Wọ́n rò pé a kò lè ṣẹ́gun wọn, a kò lè fi ọwọ́ kàn wọ́n, a kò lè fi ojú rí wọn, àti pé a kò lè pé wọ́n láti jíhìn iṣẹ́ wọn nítorípé wọ́n ń bọ́ lọ́wọ́ àwọn ìwà burúkú wọn. Onísáàmù náà tún fi ojú sì àwọn èrò rẹ̀ lórí ohun tí ó mọ̀ pé òtítọ́ ni pé: Ọlọ́run ayérayé ń wo ohun gbogbo, Ó sì mọ ohun gbogbo, Ó sì lè gbe ìjà àwọn aláìní-olùrànlọ́wọ́. Pẹ̀lú ìdúróṣinṣin oókàn-àyà àti èrò inú rẹ̀, òǹkọ̀wé náà fi ìfọ̀kànbálẹ̀ béèrè lọ́wọ́ Ọlọ́run fún ìṣírí àti ìdájọ́ òdodo.

Báwo ni kí n ṣe dáhùn?

Ojoojúmọ́ ni à ń rí i: àwọn ènìyàn aláìwà-bí-Ọlọ́run tí ń ṣe ìpalára fún àwọn ẹ̀dá ènìyàn míìràn. Ó sáábà máa ń dà bíi pé àwọn tí ń fi orúkọ àti ìdánimọ̀-ẹni já olè àti àwọn oní-sùnmọ̀mí ń borí nínú ìjà náà. A máa ń fi ọ̀rọ̀ jà fitafita, fi ọ̀rọ̀ ránṣẹ́, à ń kéde, a sì ń pa ariwo nípa ìwà ìrẹ́jẹ ní orí ayélujára, àmọ́ ìgbà mélòó ni o máa ń lọ tààrà sí ọ́dọ̀ Ẹni tí gbogbo ènìyàn yíò jíhìn fún? Àwọn ohun wo ní o ní láti lo àkókò ní orí wọn nínú àdúrà dípò kí o máa lo àkókò rẹ lori ẹ̀rọ-ìléwọ́ tàbí ní orí ayélujára? Lóòótọ́, ní ojú ayé rẹ, o lè má ríi pé a ṣe ìdájọ́ ní orí ohun tí ó mu ọ́ ní omi jùlọ. Àmọ́ ṣá o, ó dá ní l'ójú pé àwọn ènìyàn búburú àti agbéraga yíò jíhìn iṣẹ́ wọn fún Ọlọ́run Olódùmarè

Ìwé mímọ́

Nípa Ìpèsè yìí

Worship: A Study in Psalms

Àwọn sáàmù jẹ́ àkójọpọ̀ àwọn ewì àti àwọn orin tí a kọ ní ìkọjá ẹgbẹ̀rún ọdún sẹ́yìn. Bí àwọn Sáàmú ṣe ní àwọn ìyìn aláyọ̀ àti àwọn ìbànújẹ́ ọkàn, gbogbo ìwé náà jẹ́rìí sí ìfẹ́ ìdúróṣinṣin ti Ọlọ́run ní sí àwọn ènìyàn Rẹ̀ ní gbogbo ọ̀nà. Gẹ́gẹ́ bí ìwé tí ó wá ní agbedeméjì ìjọsìn Májẹ̀mú Láíláí, sáàmù kọ̀ọ̀kan ní ìrètí láti yọrí sí ìyìn Ọlọ́run nínú ikú àti àjínde Jésù Kristi.

More

Ó wù wá láti dúpẹ lọ́wọ́ ilé ìjọsìn onítẹ̀bọmi L. Camden kejì tí ó wà ní òpópónà Tọ́másì Tommy fún ìpèsè ẹ̀kọ́ yì i. Fún àlàyé ní kíkún sí i. jọ̀wọ́ kàn sí: http://www.trbc.org