Ètò Ọlọ́jọ́ Mọ́kànlélọ́gbọ̀n fún Àtúntò ÌgbéyàwóÀpẹrẹ

Láti ní ayọ̀ nínú ìgbéyàwó, o gbọ́dọ̀ ṣe ìkòsílẹ̀ ìgbéraga, àìní ìfọkànbalẹ̀ lórí olólùfẹ́, àìnísùúrú, ohun tí ó ti kọjá lọ, ìbínú, ìkorò, ẹ̀ṣẹ̀, àti ìkórira ní ọ̀pọ̀lọpọ̀ ìgbà ṣùgbọ́n o kò gbọ́dọ̀ kọ olólùfẹ́ rẹ sílẹ̀.
•••
Ẹ̀yin ará, a pe Sátánì ní ẹlẹ́tàn ńlá, kìí ṣe nítorí pé ó jẹ́ ńlá ní ọ̀nà èyíkéyìí, ṣùgbọ́n nítorí pé ó ti wà nínú ìwà búburú yìí fún ìgbà pípẹ́. O mọ ìgbà tí ó yẹ kí ó gbé ìgbésẹ̀ àti ìgbà tí kò yẹ. Ó dà bíi kìnnìún, tí ó ń bù ramúramù, tí ó sì ń yọ kẹ́lẹ́kẹ́lẹ́, tí ó ǹ dúró fún àkókò ìpalára láti tú ìgbéyàwó rẹ ká. Ó ṣe pàtàkì púpọ̀ láti mọ̀ pé ìgbéyàwó rẹ wà lórí àkọọ́lẹ́ fún ìkọlù Sátánì. Ìgbéyàwó rẹ jẹ́ ohun àfojúsùn fún ọ̀tá. Ó kórira rẹ. Ó kórira ìgbéyàwó rẹ. Àti pé ó kòrira ètò Ọlọ́run fún ìgbéyàwó rẹ. Ìdí nìyí tí ó fí ṣe pàtàkì púpọ̀ láti pinnu láti dúró lórí Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run! Àwa gẹ́gẹ́ bíí ọmọ ogun Ọlọ́run ní láti wà ní ìmúrasílẹ̀ ní ìgbà gbogbo. A gbọ́dọ̀ gb'ára dì láti jà. A gbọ́dọ̀ pé orúkọ Jésù! A gbọ́dọ̀ gbé àwọn ìgbéyàwó wa lé ọwọ́ Rẹ̀! Nítorí bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé ọ̀tá n d'ọdẹ, kò lè bá Ọlọ́run wá dọ́gba. Àmọ́ ó kù sí ọwọ́ wá láti rọ̀ mọ́ Ọlọ́run ní àárín àfonífojì tàbí láti ṣubú fún ìdùnnú èké ti Sátánì ní ọ̀nà lọ sí orí òkè tí yíò yọrí sí àbámọ̀ àti ìbànújẹ́. Nítorí ìdí èyí yàn Jésù!
Ìwé mímọ́
Nípa Ìpèsè yìí

Ǹjẹ́ o nílò ohun tí yíò mú kí ìgbéyàwó rẹ sunwọ̀n sí i? Ẹ ka Ìwé Mímọ́, kí ẹ sì bá ara yín jíròrò fún ọjọ́ mọ́kànlélọ́gbọ̀n gbáko, ẹ ó sì rí bí Jésù yíò ṣe fi ara hàn yín!
More