Ètò Ọlọ́jọ́ Mọ́kànlélọ́gbọ̀n fún Àtúntò ÌgbéyàwóÀpẹrẹ

Ohun kan tí ó maá ń tàn kálẹ̀ tí o lè mú wọ inú ìdílé rẹ ni ìṣesí rẹ. Rí i dájú pé ò ń tan ohun tí Jésù kò nílò láti wòsàn ká inú ilé rẹ.
•••
A kò lè tán ara wa ní sùúrù kí a tó rí ọkọ tàbí aya wa. Orísun oore-ọ̀fẹ́ wa kò gbọdọ̀ gbẹ ṣíwájú kí a tó rí ọkọ tàbí aya wá. A kò lè ṣe aláìní oore-ọ̀fẹ́ kí a tó rí ọkọ tàbí aya wa. A kò lè ṣe aláìní àánú. A kò lè jẹ́ oníkanra. A kò lè ṣe kí a má fí ìfẹ́ hàn. Kíni ìdí èyí? Ìdí ni pé àwọn nǹkan wọ̀nyìí ni Sàtánì ń tà, wọ́n á sì mú kí ìgbéyàwó rẹ fi orí sán ọpọ́n. Ó ṣe pàtàkì púpọ̀ láti mú ìṣesí rere wá sí ilé sí ọ̀dọ̀ ọkọ tàbí aya rẹ. Ó ṣe pàtàkì púpọ̀ pé ọkọ tàbí aya rẹ kò gba àjẹkú ìfè rẹ. Ó ṣe pàtàkì púpọ̀ làti fí Jésù hàn. Jésù ní ẹni tí ó rọrùn jùlọ làti bá gbé, nítorí náà bí a ṣe ń dà bíi Rẹ̀ sí i ní ilé wa náà yíó di ibi ààbò àti àlàáfíà. Pinnu ní òní yìí pé o ju àṣẹ́gun lọ nípasẹ̀ Krístì àti pé o lè borí ìṣesí búburú nítorí ìgbéyàwó rẹ!
Ìwé mímọ́
Nípa Ìpèsè yìí

Ǹjẹ́ o nílò ohun tí yíò mú kí ìgbéyàwó rẹ sunwọ̀n sí i? Ẹ ka Ìwé Mímọ́, kí ẹ sì bá ara yín jíròrò fún ọjọ́ mọ́kànlélọ́gbọ̀n gbáko, ẹ ó sì rí bí Jésù yíò ṣe fi ara hàn yín!
More