Ètò Ọlọ́jọ́ Mọ́kànlélọ́gbọ̀n fún Àtúntò ÌgbéyàwóÀpẹrẹ

Ọlọ́run, jọ̀wọ́ dáàbò bò wá lọ́wọ́ ohunkóhun tí ó lè ba àjọṣe wa pẹ̀lú rẹ àti ti ọkọ tàbí ìyàwó wa jẹ́.
•••
Njẹ́ o lè ronú ìgbà kan tí nnkan kan tí kò yẹ kí ó ṣẹlẹ̀ ìbá tí ṣẹlẹ̀ tí ó bá jẹ́ pé ìwọ kò fi ara rẹ sí ipò kan? Èmí lè rántí ọ̀pọ̀lọpọ̀ ìgbà tí ó ṣẹlẹ̀ sí mi. Ní ìgbà mííràn a lè yààgò fún àwọn nnkan kan nípa pé kí á kàn yẹra fún ènìyàn kan, ibì kan tàbí ohun kan. Àmọ́, ó ṣe pàtàkì kí á bèèrè fún ìtọ́ni láti ọ̀dọ̀ Ọlọ́run. Bẹ Ọlọ́run kí ó ràn ọ́ lọ́wọ́ láti yààgò fún àwọn ènìyàn, àwọn ibìkan, àti àwọn nnkan tí kò ní bu ọlá fún ọkọ tàbí ìyàwó rẹ àti ní pàápàá jùlọ ìfẹ́ rẹ fún Jésù àti ìmoore rẹ fún Àgbélébùú rẹ̀. Máṣe ba àjọṣè rẹ pẹ̀lú ọkọ tàbí ìyàwó rẹ, tàbí pẹ̀lú Ọlọ́run jẹ́ nítorí nnkan kan tí Sàtánì wọ ẹ̀wù ìgbádùn rámpẹ́ fún, ṣùgbọ́n tí ó jẹ́ pé ní òtítọ́, ìbànújẹ́ ọkàn ni òpin rẹ̀.
Ìwé mímọ́
Nípa Ìpèsè yìí

Ǹjẹ́ o nílò ohun tí yíò mú kí ìgbéyàwó rẹ sunwọ̀n sí i? Ẹ ka Ìwé Mímọ́, kí ẹ sì bá ara yín jíròrò fún ọjọ́ mọ́kànlélọ́gbọ̀n gbáko, ẹ ó sì rí bí Jésù yíò ṣe fi ara hàn yín!
More