Ètò Ọlọ́jọ́ Mọ́kànlélọ́gbọ̀n fún Àtúntò ÌgbéyàwóÀpẹrẹ

Kìí ṣe ojúṣe rẹ láti tún ìgbéyàwó rẹ ṣe. Ojúṣe rẹ ní láti ní ìfẹ̀ olólùfẹ́ rẹ pàápàá jù lọ ní ìgbà tí ó dà bíi pé ìgbéyàwó rẹ mẹ́hẹ.
•••
Ìbá rọrùn púpọ̀, ní ìgbà tí àwọn ńkan bá nira, láti kan fi ẹ̀rọ ìbánisọ̀rọ̀ rẹ sí ìpalọ́lọ́, kí o bọ́ sí inú ọkọ̀ ayọ́kẹ́lẹ́ rẹ, kí o sì wà á lọ. Ìdí tí a kò lè gba irú èyí ní ìyànjú ni pé irú ìgbésẹ̀ bẹ́ẹ̀ lè gbà Sátánì ní ààyè láti fí olólùfẹ́ rẹ sí ìnú ìjìyà. Síbẹ̀síbẹ̀, ní igbà míràn ó ṣe pàtàkì púpọ̀, ní ìgbà tí àwọn nkan bá nira, láti fi ara pamọ́. Láti béèrè l'ọ́wọ́ olólùfẹ́ rẹ tí ó bá leè yọ̀nda ìṣẹ́jú mẹ́wàá fún ọ láti bá Jésù pàdé. Jésù fi hàn wá bí èyí ṣe ṣe pàtàkì to ní ọ̀pọ̀lọpọ̀ ìgbà ní inú Bíbélì. Ó kúrò ní àárín èrò láti ní àkókò pẹ̀lú Ọlọ́run nìkan kí ó sí fún Ọlọ́run ní ààyè láti s'ọ̀rọ̀. Ní ìgbà tí àwọn ìgbà, ọjọ́ tàbí àti pàápàá àkókò aáwọ̀ bá wà ní inú ìgbéyàwó rẹ, fi Ọlọ́run ṣe àfojúsùn rẹ, má ṣe fi sí orí ṣíṣe àtúnṣe ìgbéyàwó rẹ. Ọ̀nà àbáyọ sí aáwọ̀ ìgbéyàwó tí ó wọ́pọ̀ mẹ́hẹ kìí ṣe láti mú àtúnṣe bá ìgbéyàwó rẹ bí kò ṣe láti mú àtúnṣe bá èrò ọkàn rẹ. Rọ̀ mọ́ àwọn ìlérí Ọlọ́run ní àárín ìrújú àti ohun tí ó lè dà bíi ìrúkèrúdò kí o sì fún Ọlọ́run ní ààyè láti ṣe àtúntò rẹ kí ó sì tún ọ mọ nípasẹ̀ rẹ. Bóyá ògidì iṣẹ́ àkànṣe tí Ọlọ́run ń ṣiṣẹ́ pè lórí kìí ṣe ìgbéyàwó rẹ, bí kò ṣe ìwọ fún ra rẹ.
Ìwé mímọ́
Nípa Ìpèsè yìí

Ǹjẹ́ o nílò ohun tí yíò mú kí ìgbéyàwó rẹ sunwọ̀n sí i? Ẹ ka Ìwé Mímọ́, kí ẹ sì bá ara yín jíròrò fún ọjọ́ mọ́kànlélọ́gbọ̀n gbáko, ẹ ó sì rí bí Jésù yíò ṣe fi ara hàn yín!
More