Ètò Ọlọ́jọ́ Mọ́kànlélọ́gbọ̀n fún Àtúntò ÌgbéyàwóÀpẹrẹ

Ọ̀nà tí ó dánilójú jùlọ láti yí ọwọ́ ìparun kúrò lọ́nà ìgbéyàwó rẹ ni pé kí ó yàn láti kúrò nínú ẹ̀ṣẹ̀
•••
Ó ṣe pàtàkì nínú ìgbéyàwó láti rántí pé ẹ̀ṣẹ̀ kì í kàn-án ṣe kí a kàn yẹra fún àwọn nǹkan ńlá, "bíi àátiígbọ́." Ẹ̀ṣẹ̀ ni àìgbọràn, pẹ̀lú. Kì í ṣe kí á kàn yẹra fún àwọn nǹkan bí àgbèrè, bákan náà ni ó jẹ́ àì ka ohùn Ọlọ́run sí tàbí ohùn tí Ó ń tọ́ka. Bí Ọlọ́run bá bá ọ sọ̀rọ̀ kẹ́lẹ́kẹ́lẹ́ pé kí ó dìmọ́ aya tàbí ọkọ rẹ kí o sì sọ fún wípé ó fẹ́ràn rẹ̀, láàárín ìjíròrò tàbí èdèkòyédé tó lè koko, tí o sì kọ̀ láti ṣe bẹ́ẹ̀ ẹ̀ṣẹ̀ ni fún ọ. Tí Ọlọ́run bá sì sọ fún ọ pé kí ó tẹ àtẹ̀jíṣẹ́ ránṣẹ́ wípé kí ó má bínú ṣùgbọ́n ìgbéraga rẹ ṣe ìdènà fún ọ, ìyẹn náà ẹ̀ṣẹ̀ ni fún ọ pẹ̀lú. Sátánì kò ní sọ fún ọ láti ni inúrere tàbí ìdáríjì sì ọkọ tàbí aya rẹ, torí náà tí ó bá ti ní ìmọ̀lára àwọn àmì wọ̀nyí, dúpẹ́ lọ́wọ́ Ọlọ́run bí Ó ṣe Ńṣe àbójútó ìgbéyàwó rẹ kí o sì gbọ́ràn síi.
Ìwé mímọ́
Nípa Ìpèsè yìí

Ǹjẹ́ o nílò ohun tí yíò mú kí ìgbéyàwó rẹ sunwọ̀n sí i? Ẹ ka Ìwé Mímọ́, kí ẹ sì bá ara yín jíròrò fún ọjọ́ mọ́kànlélọ́gbọ̀n gbáko, ẹ ó sì rí bí Jésù yíò ṣe fi ara hàn yín!
More