Ètò Ọlọ́jọ́ Mọ́kànlélọ́gbọ̀n fún Àtúntò ÌgbéyàwóÀpẹrẹ

Ọlọ́run, tí n kò bá rí ìyàwó mi bí Ìwọ ti ń rí i, jọ̀wọ́ yo ìbòjú mi kúrò.
•••
Ní ìgbà míràn o rọrùn láti rí ọkọ tàbí aya wa fún ohun tí wọ́n ṣe dípò ohun tí wón jẹ́ lọ. Ó rọrùn láti rí àìsedéédé tàbí àìlera wọ́n dípò okun wọ́n. Ó rọrùn láti rí ìkọsẹ̀ wọ́n dípò ìlọsíwájú wọ́n. Bí ó ti wù kí ó rí, ìdàkejì bí Ọlọ́run ṣe ń wò wá nìyẹn. Ọlọ́run n wò wá pẹ̀lú ojú ìfẹ́. Ó rí ohun tí ó dára jù lọ nípa wa, pàápàá ní àwọn àkókò tí ó burú jù lọ. Òhun ni olùfẹ́ wa tí ó tóbi jù lọ. Òhun ni ọ̀rẹ́ wa tí ó ga jù lọ. Ọ̀nà tí Ó fi ń wò wá, bẹ́ẹ̀ ni ó ṣe yẹ kí a máa wo ọkọ tàbí aya wa. Olúgbani-níyànjú, kìí ṣe aláròyé. Olùforíjì, kìí ṣe adinú. Ó wà fún wa, kò lòdì sí wa.
Ìwé mímọ́
Nípa Ìpèsè yìí

Ǹjẹ́ o nílò ohun tí yíò mú kí ìgbéyàwó rẹ sunwọ̀n sí i? Ẹ ka Ìwé Mímọ́, kí ẹ sì bá ara yín jíròrò fún ọjọ́ mọ́kànlélọ́gbọ̀n gbáko, ẹ ó sì rí bí Jésù yíò ṣe fi ara hàn yín!
More