Ètò Ọlọ́jọ́ Mọ́kànlélọ́gbọ̀n fún Àtúntò ÌgbéyàwóÀpẹrẹ

Ìbáṣepọ̀ rẹ pẹ̀lú ọkọ tàbí aya rẹ kò gbọ́dọ̀ ṣe àtúnṣe sí ìbáṣepọ̀ rẹ pẹ̀lú Ọlọ́run, ṣùgbọ́n ìbáṣepọ̀ rẹ pẹ̀lú Ọlọ́run ni ó gbọ́dọ̀ ṣe àtúnṣe sí àjọṣe rẹ pẹ̀lú ọkọ tàbí aya rẹ.
•••
Ìgbà mélòó ni o dúró fún ìṣẹ́jú-àáyá láti ronú ṣáájú kí o tó fèsì? Ìgbà mélòó ni o dá dúró láti gba àdúrà ṣáájú kí o tó bèrù? Gẹ́gẹ́ bíi Krìstìẹ́nì, ó ṣe pàtàkì gan-an pé kí a má ṣe fi bí nkan ṣe rí ní ara wá ṣe àkọ́kọ́, nítorí ní ìgbà míràn, bí nkan ṣé rí ní ara wa kìí jẹ́ kí a sọ tàbí ṣe nnkan ti Ọlọ́rún. Nítorí ìfẹ́ wa fún Ọlọ́run àti ìgbéyàwó wa, ó ṣe pàtàkì gan-an láti ya ìṣẹ́jú kan sí ọ̀tọ̀ láti mú ọkàn àti ìrònú wa dọ́gba pẹ̀lú Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run, kí a baà leè fèsì tí ń fi ògo fún Jésù. A ní láti bẹ̀rẹ̀ síí béèrè l'ọ́wọ́ Ọlọ́run ní ọ̀pọ̀ ìgbà láti mú ọkàn wa wà ní ìṣọ̀kan pẹ̀lú Rẹ̀ kí ìṣe wa leè tẹ̀lé àpẹẹrẹ Rẹ̀, àti kí àwọn ìrònú wa leé bá ọ̀nà Rẹ̀ mu. Bí a bá ṣe ń pa ọkàn pọ̀ sí orí Ọlọ́run tó, bẹ́ẹ̀ náà ni ìgbéyàwó wa yóò ṣe ní ẹwà tó.
Ìwé mímọ́
Nípa Ìpèsè yìí

Ǹjẹ́ o nílò ohun tí yíò mú kí ìgbéyàwó rẹ sunwọ̀n sí i? Ẹ ka Ìwé Mímọ́, kí ẹ sì bá ara yín jíròrò fún ọjọ́ mọ́kànlélọ́gbọ̀n gbáko, ẹ ó sì rí bí Jésù yíò ṣe fi ara hàn yín!
More