Ètò Ọlọ́jọ́ Mọ́kànlélọ́gbọ̀n fún Àtúntò ÌgbéyàwóÀpẹrẹ

31 Day Marriage Reset

Ọjọ́ 28 nínú 31

Bóyá o wọ ìgbéyàwó rẹ láì ní ìrètí pé yíò rí bí ó ti jẹ́ ní báyìí, ṣùgbọ́n Ọlọ́run mọ̀. Bá A s'ọ̀rọ̀ nípa rẹ̀. 

•••

Njé ọ ti bẹ̀ẹ̀rẹ̀ ńkań ní ireti pé yíò já sí ọ̀nà kan, ṣùgbọ́n ó lọ ní ìdàkẹjì? Bí mo ti ní ìrètí pé èyí kìí ṣe nípa ìgbéyàwó rẹ mo fẹ́ kí o mọ̀ pé ìwọ nìkan kọ́ ni o wa nínú ipò yìí. Mo ní èrò pé èyí máa n ṣẹlẹ̀ sí ọ̀pọ̀lọpọ̀ ènìyàn. O wọ ìgbéyàwó pẹ̀lú ọ̀yàyà àti ìfẹ̀, o sì ní arinrin ni ìbẹ̀rẹ̀pẹ̀pẹ̀. Lẹ́yìn náà ni ìrírí iṣẹ́, ẹbí àti ọ̀pọ̀lọpọ̀ àwọn ohun òmíràn bẹ̀ẹ̀rẹ̀ sí níí já pọ̀. Ara bẹ̀ẹ̀rẹ̀ sí níí silé, àwọn ohun tí ó máa n mú ara rẹ yá gágá sí bẹ̀ẹ̀rẹ̀ sí níí kọjá lọ. Èyí jẹ́ déédé àmọ́ má ṣe fi èyí ṣe òṣùwọ̀n. Béèrè ní ọwọ́ Ọlọ́run kí Ó dá ọ̀yàyà náà padà. Béèrè kí Ó fi hàn ọ́ àwọn ọ̀nà titun tí o lè fi bùkún olólùfẹ́ rẹ. Béèrè kí Ó jẹ́ kí ìgbéyàwó rẹ kún fún agbára kí Ó sì lò ọ́ ní ọ̀nàkọnà tí Ó lè lò ọ́. Bóyá àsìkò ti tó láti gbàgbé àwọn ohun tí a sọ tàbí ṣe ní àṣẹ̀yìnwá. Béèrè kí Olọ́run ràn ọ́ l'ọ́wọ́ láti mú gbogbo ẹ̀gbin ọkàn kúrò, èyí tí ó n dí ọ l'ọ́wọ́ láti ní ìbáṣepọ̀ tímọ́ tímọ́ tí o ní tẹ́lẹ̀. Olọ́run fẹ́, Ó sì lè mú padà bọ́ sí'pò, o kàn ní láti pinnu láti má fi ipò tí o wà ṣe òṣùwọ̀n. 

Ìwé mímọ́

Nípa Ìpèsè yìí

31 Day Marriage Reset

Ǹjẹ́ o nílò ohun tí yíò mú kí ìgbéyàwó rẹ sunwọ̀n sí i? Ẹ ka Ìwé Mímọ́, kí ẹ sì bá ara yín jíròrò fún ọjọ́ mọ́kànlélọ́gbọ̀n gbáko, ẹ ó sì rí bí Jésù yíò ṣe fi ara hàn yín!

More

A fẹ́ dúpẹ́ lọ́wọ́ ìjọ Stonecreek fún ìpèsè ètò yìí. Fún àlàyé síwájú síi, jọ̀wọ́ lọ sí: http://www.stonecreek.church