Ètò Ọlọ́jọ́ Mọ́kànlélọ́gbọ̀n fún Àtúntò ÌgbéyàwóÀpẹrẹ

Òní jẹ́ ọjọ́ tí ó dára láti yan ọjọ́ tí ó dára.
•••
Ní ìgbà míràn àwọn ọjọ́ rere kìí déédé wá fúnraa wọn. Òwúrọ̀ lè lọ́ ojú pọ̀, kí táyà ọkọ̀ ẹnìkan jò dànù, kí a mú iná mànàmáná lọ, abbl. Ní ìgbà míràn àwọn ǹǹkan yíó ṣẹlẹ̀ tí yíó mú kí a wòye pé ọjọ́ burúkú èṣù gbomimu gbáà ni. Àmọ́, èyí kò yẹ kí ó rí bẹ́ẹ̀! Àmọ́ ṣá, ó ní láti jẹ́ ìpinnu rẹ. Ní ìgbà mìíràn, a lè wà ní ipò kan tí yíó mú wa ní ìṣesí búburú nípa ìṣẹ̀lẹ̀ kan tí kò dára, tàbí kí a dúpẹ́ l'ọ́wọ́ Ọlọ́run fún gbogbo ìbùkún tí ó wà nínú ìgbésí ayé wa. Òní jẹ́ ọjọ́ tí ó dára láti yan ọjọ́ tí ó dára. Kì í ṣe nítorí bí ọjọ́ ṣe rí, bí kò ṣe nítorí pé Ọlọ́run dára sí ọ́ gan-an. Jẹ́ kí ọjọ́ òní jẹ́ ọjọ́ tí ìwọ yíó bẹ̀rẹ̀ sí í ronú nípa àwọn ìbùkún rẹ dípò tí ìwọ á fi máa ronú nípa ipò tí o wà.
Ìwé mímọ́
Nípa Ìpèsè yìí

Ǹjẹ́ o nílò ohun tí yíò mú kí ìgbéyàwó rẹ sunwọ̀n sí i? Ẹ ka Ìwé Mímọ́, kí ẹ sì bá ara yín jíròrò fún ọjọ́ mọ́kànlélọ́gbọ̀n gbáko, ẹ ó sì rí bí Jésù yíò ṣe fi ara hàn yín!
More