Ètò Ọlọ́jọ́ Mọ́kànlélọ́gbọ̀n fún Àtúntò ÌgbéyàwóÀpẹrẹ

31 Day Marriage Reset

Ọjọ́ 26 nínú 31

Kódà bí ọkọ tàbí àyà rẹ kò bá ṣe bí ó ti tọ́, ìwọ gbọdọ̀ ṣe bẹ́ẹ̀.

•••

Ní àkókò kan, mo wà ní ibi àpérò kan tí olùbánisọ̀rọ̀ náà sì ń sọ nípa bí wọ́n ṣe wà ní àkókò ọ̀dá, tí ó sì ṣòro fún wọn láti gbọ́ ohùn Ọlọrun. Wọ́n sọ pé ní ìgbà tí àwọn wà ní àkókò yẹn, ní ìwọ̀n bí àwọn kò ti mọ ìgbésẹ̀ tí ó yẹ kí àwọ́n tẹ̀lé tàbí ọ̀nà tí Ọlọ́run ń pè àwọn sí, ohun kan ṣoṣo tí àwọn mọ̀ láti ṣe ni pé kí àwọn máa gbé ní ìbámu pẹ̀lú Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run. Láti jí ní ojoojúmọ́ ní àsìkò náà kí wọ́n sì sọ pé, "Ọlọ́run, mo fi ọjọ́ yìí fún ọ. Ràn mí l'ọ́wọ́ láti gbé ìgbé ayé tí ó ń fi ògo fún ọ." Mo rò pé èyí ní agbára gan-an ni. Pé ní ìgbà tí a kò bá mọ ohun tí a yíò ṣe, a lè ṣe ohun tí ó tọ́. A lè  tẹ̀ síwájú láti jẹ́ olóòótọ́ ní gbogbo ìgbà. Mo tún fẹ́ràn bí ìwàásù náà ṣe parí. Wọ́n sọ pé ní àsìkò náà, ní ọjọ́ kan, wọ́n jí, wọ́n sì gbọ́ tí Ọlọ́run sọ ní kedere pé, "Ó ti parí". Ní ọjọ́ náà ni àkókò yẹn dé opin, Ọlọ́run sì bẹ̀ẹ̀rẹ̀ sí í darí wọn ní ọ̀nà tí ó hàn kedere. Ní ìgbà míràn a máa ń la àwọn àsìkò tí kì í ṣe ti ìdùnnú, tí kò ní ayọ̀ kọjá, tí ó jẹ́ pé ó máa ń nira gan-an, ṣùgbọ́n a ṣì ń pè wá láti jẹ́ olóòótọ́ nínú dídúró. Bí o bá wà ní inú ọ̀kan nínú àwọn àsìkò wọ̀nyìí, ní ìgbà tí o bá ń dúró, fi ara rẹ fún Ọlọ́run, kí o sì yàn láti ṣe ohun tí ó tọ́.

Ìwé mímọ́

Nípa Ìpèsè yìí

31 Day Marriage Reset

Ǹjẹ́ o nílò ohun tí yíò mú kí ìgbéyàwó rẹ sunwọ̀n sí i? Ẹ ka Ìwé Mímọ́, kí ẹ sì bá ara yín jíròrò fún ọjọ́ mọ́kànlélọ́gbọ̀n gbáko, ẹ ó sì rí bí Jésù yíò ṣe fi ara hàn yín!

More

A fẹ́ dúpẹ́ lọ́wọ́ ìjọ Stonecreek fún ìpèsè ètò yìí. Fún àlàyé síwájú síi, jọ̀wọ́ lọ sí: http://www.stonecreek.church