Ètò Ọlọ́jọ́ Mọ́kànlélọ́gbọ̀n fún Àtúntò ÌgbéyàwóÀpẹrẹ

Kò gbọdọ̀ sí ohunkóhun tí ò n fi pamọ́ fún ọkọ tàbí aya rẹ. Ìwọ àti gbogbo ìṣe rẹ ní láti hàn kedere sí i.
•••
O ní láti jẹ́ ẹni tí ó ṣe é fi ọkàn tán pátápátá láì sí ohunkóhun tí ó jẹ àṣírí fún olólùfẹ́ rẹ. Kò gbọdọ̀ sí ohunkóhun ní ibi kọ́lọ́fín inú rẹ tí kò ní hàn ní gbangba sí ọkọ tàbí aya rẹ àti Ọlọ́run pẹ̀lú. Kò gbọdọ̀ sí ohun kan tí o nílò láti bò fún ẹnìkejì rẹ. Bí irú rẹ̀ bá wà, ó ṣeé ṣe kí ó jẹ́ wípé nítorí pé Sátánì ti fi dá ọ lójú pé ó yẹ kí ó rí bẹ́ẹ̀, nítorí pé àṣeyọrí wà ní òdì-kejì òtítọ́ rẹ. Òdodo ọ̀rọ̀ kò rọrùn láti gba tàbí láti jẹ́wọ́ rẹ, ṣùgbọ́n ó jẹ́ ohun àmúyẹ. Jẹ́ kí ọjọ́ òní jẹ́ ọjọ́ tí ó jẹ́ pé tí àṣírí kan bá wà, ṣí i sí gbangba. Béèrè ní ọwọ́ Ọlọ́run láti darí rẹ kí ó ràn ọ l'ọ́wọ́ láti gbé ìgbésí ayé láì sí àṣírí nínú ìgbéyàwó rẹ. Òtítọ́ ní gbogbo ọ̀nà á mú òmìnira wá láti jẹ́ ẹni tí o jẹ́ àti láti ní ìmọ̀lára ìtẹ́wọ́gbà àti ẹni tí a ní ìfẹ́ sí.
Ìwé mímọ́
Nípa Ìpèsè yìí

Ǹjẹ́ o nílò ohun tí yíò mú kí ìgbéyàwó rẹ sunwọ̀n sí i? Ẹ ka Ìwé Mímọ́, kí ẹ sì bá ara yín jíròrò fún ọjọ́ mọ́kànlélọ́gbọ̀n gbáko, ẹ ó sì rí bí Jésù yíò ṣe fi ara hàn yín!
More