Ètò Ọlọ́jọ́ Mọ́kànlélọ́gbọ̀n fún Àtúntò ÌgbéyàwóÀpẹrẹ

Ẹni àìmọ̀ ni ọjọ́ iwájú jẹ, ṣùgbọ́n tí ẹ̀yin méjèèjì bá dojú kọ Ẹni tí ó ní ọjọ́ iwájú yin ní ìkáwọ́, ìgbà náà ni èyíkéyìí nínú ẹ̀yin méjèèjì kò ní ṣe àníyàn nípa ohun tí ọjọ́ ọ̀la yín mú dání.
•••
Ẹ̀rù... Eh... Ẹ̀rù jẹ́ èké síbẹ̀síbẹ̀ ó rọrùn láti gbá á gbọ́. Ó rọrùn púpọ̀ láti ba ara jẹ́ ní ìgbà tí àwọn ìnáwó kò bá tó gbèsè tí a jẹ. Tàbí tí olùfẹ́ wa kan bá ń ṣe àìsàn. Tàbí ní ìgbà tí ọkọ̀ ayọ́kẹ́lẹ́ wa bá yọnu. Tàbí ní ìgbà tí ________... Ìwọ náà lẹ parí èyí tí ó kù. Ọ̀pọ̀lọpọ̀ àyídáyidà àti ipò oríṣiríṣi ni ó ń fa ìbẹ̀rù fún wa. Ní ìgbà gbogbo ni ìbẹ̀rù máà ń gbìyànjú láti rápálá wọ inú ìgbésí ayé àti ìgbéyàwó wá pẹ̀lú. Àmọ́ Ọlọ́run tí à ń sìn jẹ́ Eni tí a lè gbé ọkàn àti àfojúsùn lé ju àwọn irọ́ tí ó lè mú wá sìnà kí ó sì ṣe àkóbá fún ìgbéyàwó wá lọ. Òní yìí ni ọjọ́ tí ó yẹ kí o sọ ìdààmú rẹ di ìyìn kí o sì dúpẹ l'ọ́wọ́ Ọlọ́run pé kò sí ohun kan tí o lè ṣe àníyàn lè lórí. Dúpẹ́ l'ọ́wọ́ Rẹ pé o lè gbà Á gbọ́ pẹ̀lú kí o sì sọ fún Sátánì pé ìwọ kò gba irọ́ rẹ gbọ mọ́.
Bí ìbẹ̀rù bá ń gbìyànjú láti kó ìdààmú bá ọ ní òní, kí o tó gbà ní ààyè láti ṣe àkóso rẹ, béèrè ní ọwọ́ ara rẹ bí ó bá n dààmú Ọlọ́run. Kò rí bẹ́ẹ̀ rárá, nítorí pé Ó ti ní ètò nípa rẹ tẹ́lẹ̀tẹ́lẹ̀.
Ìwé mímọ́
Nípa Ìpèsè yìí

Ǹjẹ́ o nílò ohun tí yíò mú kí ìgbéyàwó rẹ sunwọ̀n sí i? Ẹ ka Ìwé Mímọ́, kí ẹ sì bá ara yín jíròrò fún ọjọ́ mọ́kànlélọ́gbọ̀n gbáko, ẹ ó sì rí bí Jésù yíò ṣe fi ara hàn yín!
More