Ètò Ọlọ́jọ́ Mọ́kànlélọ́gbọ̀n fún Àtúntò ÌgbéyàwóÀpẹrẹ

31 Day Marriage Reset

Ọjọ́ 6 nínú 31

Ohun kan tí a ti kọ́ ní pé ìgbádùn ni fún wa bí a bá n bá ara wa ṣe eré. Láti rín ẹ́rín àti láti pa ẹlòmíràn ní ẹ̀rín. Ṣùgbọ́n jú gbogbo rẹ̀ lọ láti yan ayọ̀ ní ìgbà tí Sátánì ń pariwo ìdàkejì.

•••

Òní ni ọjọ́ tí ó yẹ láti jo ní inú ilé ìdáná. Láti rín títí lọ kí a sì pé eré-ìjé títí dé ibi àmì tí a ní láti dúró. Láti gbádùn ara wa! Ọjọ́ òní ni ó yẹ kí a yàn gẹ́gẹ́ bíi ọjọ́ ayọ̀. Sátánì máà ń gbìyànjú ní ìgbà gbogbo láti mú wa bínú, bẹ̀rù, másùnmáwo, dààmú àti ohun òmíràn kí a máa bà gbádùn àkókò pẹ̀lú ọkọ tàbí aya wa. Ṣùgbọ́n èyí jẹ́ dandan bíi ọmọ Ọlọ́run láti sinmi nínú àwọn ìlérí Rẹ̀ àti láti gbádùn ìgbésí ayé ojoojúmọ́. Ọlọ́run dára, a sì lè gbàgbọ́ wí pé yíò ṣe ohun wọ̀n-ọnní tí àwa kò lè ṣe. Yan ayọ̀ ní òní nítorí pé ìrètí rẹ wà ní ọ̀dọ̀ Ọlọ́run. Má ṣe wo àwọn ipò, wo aya tàbí ọkọ rẹ àti ju gbogbo rẹ̀ lọ wo Ọlọ́run rẹ. Rántí pé ọjọ́ ìbùkún ni òní kí o sì ṣe ohun dídára pẹ̀lú rẹ̀. 

Yan ayọ̀ ní òní!

Ìwé mímọ́

Nípa Ìpèsè yìí

31 Day Marriage Reset

Ǹjẹ́ o nílò ohun tí yíò mú kí ìgbéyàwó rẹ sunwọ̀n sí i? Ẹ ka Ìwé Mímọ́, kí ẹ sì bá ara yín jíròrò fún ọjọ́ mọ́kànlélọ́gbọ̀n gbáko, ẹ ó sì rí bí Jésù yíò ṣe fi ara hàn yín!

More

A fẹ́ dúpẹ́ lọ́wọ́ ìjọ Stonecreek fún ìpèsè ètò yìí. Fún àlàyé síwájú síi, jọ̀wọ́ lọ sí: http://www.stonecreek.church