Ètò Ọlọ́jọ́ Mọ́kànlélọ́gbọ̀n fún Àtúntò ÌgbéyàwóÀpẹrẹ

Máà mú orí olólùfẹ́ rẹ yà ni ojoójúmọ́
•••
Ṣe kóríyá ni kíkún fún olólùfẹ́ rẹ. Ṣe àpọ́nlé yí ni gbangba àti ní ìkọ̀kọ̀. Jẹ́kí ó mọ̀ wípé òun ni ó tẹjú mọ́ àti wípé ó rí ohun tí ó dára jù lọ nínú rẹ. Kì í ṣe pé yóò gbé e lárugẹ nìkan, ṣùgbọ́n yóò mú ara ìwọ pàápàá yá gágá. Gẹ́gẹ́ bí ẹni kọ̀ọ̀kan, a fẹ́ràn apọnle ara ẹni nínú ìgbéyàwó wá. Ó jẹ́ ohun tí ó mú ọkàn yọ̀ ó tí a bá pọ́n ni lé, tí a sì pọ́n ẹlòmíràn lé pẹ̀lú. Fún àpẹẹrẹ, tí ó bá jí tí ó sì rí olólùfẹ́ rẹ bí ó ṣe dúró déédéé, sọ fún. Tí olólùfẹ́ rẹ bá se oúnjẹ́ aládùn ni alẹ́, jẹ́kí ó mọ bí ó ṣe dùn tó. Bí olólùfẹ́ rẹ bá ṣe ilé rẹ lọ́ṣọ́, jẹ́kí ó mọ wípé nǹkan tí ó dára ní ó ṣe. Bí olólùfẹ́ rẹ bá ṣiṣẹ́ kára láti pèsè àwọn ohun amuyẹ́ ni ilé, jẹ́kí ó mọ pé ìwọ náà mọ rírí ìlà kàkà rẹ̀ nípa fi fi ẹ̀mí imoore hàn. Bí olólùfẹ́ rẹ bá jẹ́ olóòótọ́ ènìyàn, jẹ́kí ó mọ bí ó ṣe gbé ọ nìyí tó fún ìwà daradara bayi. Apọnle a máà fún ní ní ìtura ọkàn, a kò sì gbàgbọ́ wípé ó lè fún ní ní àpọ̀jù!
Ìwé mímọ́
Nípa Ìpèsè yìí

Ǹjẹ́ o nílò ohun tí yíò mú kí ìgbéyàwó rẹ sunwọ̀n sí i? Ẹ ka Ìwé Mímọ́, kí ẹ sì bá ara yín jíròrò fún ọjọ́ mọ́kànlélọ́gbọ̀n gbáko, ẹ ó sì rí bí Jésù yíò ṣe fi ara hàn yín!
More