Ètò Ọlọ́jọ́ Mọ́kànlélọ́gbọ̀n fún Àtúntò ÌgbéyàwóÀpẹrẹ

31 Day Marriage Reset

Ọjọ́ 2 nínú 31

Tí ó bá kojú ìṣòrò nínú ìgbéyàwó rẹ, ìwọ kò gbọ́dọ̀ dáwọ́ dúró láti kópa nínú ìgbéyàwó rẹ, ṣe ni ó ní láti dẹ́kun áti kópa nínú ìṣòro náà.

•••

Nígbà míràn ó rọrùn láti fà sẹ́yìn kí a má ṣe bá ara wa sọ̀rọ̀ nígbàtí inú wa bá ń ru si olólùfẹ́ wa. Ó rọrùn láti tẹ́tí sí ohùn kẹ́lẹ́kẹ́lẹ́ yẹn tí ó ń sọ fún wa wípé "Èmi kò tilẹ̀ ni sọ̀rọ̀ nítorí ______.” Fí èyí tó kú kún. Síbẹ̀, sìṣọ̀rọ̀ sókè àti bíbá ara ẹni sọ àwọn ọ̀rọ̀ tí kò rọrùn nígbà míràn yí ni kọ́kọ́rọ́ tí yóò dẹ́kun kí á máa ní ìrúnú sí ara wa ní gbogbo ìgbà lórí ọ̀rọ̀ kan náà ṣá. Bí ó bá fẹ́ láti ka 1 Kọ́ríńtì 13 kí ó tó bá olólùfẹ́ rẹ sọ̀rọ̀ nípa ohunkóhun tí ó bà ọ́ lọ́kàn jẹ, ṣe bẹ́ẹ̀ gẹ́gẹ́. Ṣùgbọ́n má ṣe pa ẹnu mọ́ kí ó sì rò pé ọ̀rọ̀ náà á yanjú fúnra rẹ̀. Ní ìmúra pé oó ṣe ohunkóhun tí ó bá gba bákannáà ẹ ó sì ní ìbára-eni-sọ̀rọ̀ tí ó yẹ láàárín tọkọtaya kí ó tó di pé àìṣe wọ́n yóò mú ìfàsẹ́yìn bá ìgbéyàwó yín, àti àìlè gbèrú tó bí ó ṣe yẹ kí ẹ tó.

Ìwé mímọ́

Nípa Ìpèsè yìí

31 Day Marriage Reset

Ǹjẹ́ o nílò ohun tí yíò mú kí ìgbéyàwó rẹ sunwọ̀n sí i? Ẹ ka Ìwé Mímọ́, kí ẹ sì bá ara yín jíròrò fún ọjọ́ mọ́kànlélọ́gbọ̀n gbáko, ẹ ó sì rí bí Jésù yíò ṣe fi ara hàn yín!

More

A fẹ́ dúpẹ́ lọ́wọ́ ìjọ Stonecreek fún ìpèsè ètò yìí. Fún àlàyé síwájú síi, jọ̀wọ́ lọ sí: http://www.stonecreek.church