Ètò Ọlọ́jọ́ Mọ́kànlélọ́gbọ̀n fún Àtúntò ÌgbéyàwóÀpẹrẹ

Kristi kìí máà mú àwọn àṣìṣe àti ìkùnà láti ìgbà àtijọ́ wá sí ìrántí bíkòṣe ìṣe ọwọ́ Sátánì
•••
Jésù ní inú dídùn sí ọ. Ó fẹràn rẹ! Àánú Rẹ̀ jẹ ọ̀tun ni òwòwúrọ̀. Ó Ǹ fà ọ mọ́ra loni. Sátánì, ní tìrẹ a máà mú àwọn àkókò tí ó ṣe àṣìṣe wá sí ìrántí rẹ, a sì máa ohun tí ó tí kọjá lọ pọ́n ọ lójú. Sátánì a rú àwọn àṣìṣe rẹ sókè bí ó ṣe ń gbìyànjú lati jẹ ki ojú kì ó tí ọ kí ó sì di aláìyẹ. O ṣe ppàtàkì gan fún ọ lati bèèrè lọ́wọ́ ara rẹ ẹni ti ó fí ìgbéyàwó rẹ jọ? Ǹjẹ́ ó ń bá olólùfẹ́ rẹ lò ní bí ojúmọ́ ṣe ń mọ́, tàbí ṣe ní ó ń tẹjúmọ́ àṣìṣe tí àná? Béèrè lọ́wọ́ Ọlọ́run ni òwúrọ̀ ọjọ́ kọ̀ọ̀kán kí Ó ràn ọ lówọ́ lati ṣe àfihàn ifẹ ati ìdáríjì Rẹ̀ nínú ìgbéyàwó rẹ.
Ìwé mímọ́
Nípa Ìpèsè yìí

Ǹjẹ́ o nílò ohun tí yíò mú kí ìgbéyàwó rẹ sunwọ̀n sí i? Ẹ ka Ìwé Mímọ́, kí ẹ sì bá ara yín jíròrò fún ọjọ́ mọ́kànlélọ́gbọ̀n gbáko, ẹ ó sì rí bí Jésù yíò ṣe fi ara hàn yín!
More