Ètò Ọlọ́jọ́ Mọ́kànlélọ́gbọ̀n fún Àtúntò ÌgbéyàwóÀpẹrẹ

Tí o kò bá lè ronú ìdí kan láti dúró pẹ̀lú ọkọ tàbí aya rẹ, rántí pé Jésù lọ sí orí igi Agbelebu fún ọ ní ìgbà tí o kò wúlò fún. Ó pa májẹ̀mú Rẹ̀ mọ́ pẹ̀lú rẹ ní ìgbà tí o kò fún-Un ní ìdí kan ṣoṣo láti ṣe bẹ́ẹ̀.
•••
Njẹ́ o dà bíi pé okùn kan ló kù tí ó n gbé ìgbéyàwó rẹ ró? Bíi ẹni pé okùn tí ó so yín pọ̀ tẹ́lẹ̀ tí tú, o kò sì mọ̀ bí ó ṣe lè dì yín mú pẹ́ tó. Yàtọ̀ sí èrò ọkàn rẹ tàbí ohun tí Sátánì lè máà sọ fún ọ, kì í ṣe ohun tí kò ní àtúnṣe! Ọlọ́run ìmúpadà-bọ̀sípò àti ìràpadà ni à ń sìn. Ṣíwọ́ láti máà wo okùn tí ó tú kí o sì wo Ọlọ́run oníṣẹ́ ìyanu wá. Tí àwọn ènìyàn kan bá wà tí wọ́n n sọ ọ̀rọ̀ òdì nípa ìgbéyàwó rẹ tí wọ́n sì ń pe àkíyèsí rẹ sí okùn tí ó tú, àkókò ti tó láti rán wọn, àti ìwọ pàápàá létí, pé bí Jésù bá lè jí òkú dìde, Ó lè ṣe àjínde ìgbéyàwó tí ó kú pẹ̀lú. Ọlọ́run fẹ́ràn rẹ Ó sì fẹ́ràn ìgbéyàwó rẹ pẹ̀lú. Ó fẹ́ rí ìṣọ̀kan nínú ìgbéyàwó rẹ pàápàá jù bí ìwọ ti fẹ́ ẹ lọ. Ìgbéyàwó rẹ kìí ṣe ohun àwàdà rárá kìí ṣìí ṣe ohun tí Ó fi ọwọ́ yẹpẹrẹ mú. Dúró ṣinṣin kí o rọ̀ mọ́ ọ̀rọ̀ Ọlọ́run àti ìṣòdodo Rẹ̀. Ó ń jà fún ìgbéyàwó rẹ.
Ìwé mímọ́
Nípa Ìpèsè yìí

Ǹjẹ́ o nílò ohun tí yíò mú kí ìgbéyàwó rẹ sunwọ̀n sí i? Ẹ ka Ìwé Mímọ́, kí ẹ sì bá ara yín jíròrò fún ọjọ́ mọ́kànlélọ́gbọ̀n gbáko, ẹ ó sì rí bí Jésù yíò ṣe fi ara hàn yín!
More