Ìyìn: Àṣàrò nínú Orin DáfídìÀpẹrẹ

Worship: A Study in Psalms

Ọjọ́ 57 nínú 106

Kíni ó sọ?

À dán Ásáfù wo nípa ṣíṣe ìlara aásìkí àwọn ènìyàn búburú

Kíni ró túmọ̀ sí?

Ìdààmú tí ó ní agbára dé bá Ásáfù nípa ìyàtọ̀ tó wà láàrín aásìkí àwọn ẹni burúkú àti ìṣòro àwọn olódodo. Bó tilẹ̀ jẹ́ pé ìgbéraga wọn sì Ọlọ́run àti ìwà ìkà wọn sì àwọn miran, àwọn àìwà-bi-Ọlọ́run kò ń ṣe àníyàn púpọ̀ ni ìwọ̀n ìgbà tí wọ́n ní ìlera pípé àti ọrọ̀. Ìgbésí ayé rẹ̀ kún fún ọ̀pọ̀lọpọ̀ ìṣòro àti ewu. Ó fẹ́rẹ̀ẹ́ jẹ́ kí ìdẹwò náà mú kó ṣe ìlara aásìkí wọn; nígbà náà, ó rántí pé Ọlọ́run yóò ṣè ìdájọ́ àwọn tí kò mọ Ọlọ́run, ṣùgbọ́n àwọn olódodo yóò wà lábẹ́ ààbò Rẹ̀. Ìwà-bí-Ọlọ́run Ásáfù mú èrè ayérayé wá fún àwọn àtọmọdọ́mọ rẹ̀, bí àwọn olórin ṣe kọrin ni àkókò ìsọjí ńlá tí adarí awọ́n ọmọ Ísírẹ́lì síwájú wọn láti fi ìpìlẹ̀ ilé ìjọsìn lélẹ̀ (Ẹ́sírà 3:10).

Bawo ló ṣe yẹ kí n dáhùn?

Ọlọ́run jẹ́ ẹni pípé, ó sì máa ń kíyè sí bí a ṣe ń lò ìgbésí ayé wa. Òun nìkan ṣoṣo sì ni aláṣẹ tòótọ́. Kódà nígbà tó bá dà bíi pé ìwà ibi kò ní jìyà, tó sì dà bíi pé ìwà àìwa-bí-Ọlọ́run Ọlọ́run ló wá ní ìṣàkóso, a lè ní ìdánilójú pé Ọlọ́run ń fẹ́ kí òṣùwọ̀n wọn kún ni. Alakoso gbogbo wa yóò jẹ́ ibi ààbò fún tí ó bá sinmi lè. Bí o bá yàn láti gbé ojú agan sí i, Olúwa yóò ṣe lòdì sí ọ. Ìsinmi tàbí àtakò – èwo ni ìwọ yóò yàn lónìí? Ṣé ó ṣe tán láti ṣe àwárí ìtùnú nínú àṣẹ Ọlọ́run dípò tí yóò fi máa ṣàníyàn nípa bí nǹkan ṣe ń lọ déédéé fún áwọn alàìwà-bí-Ọlọ́run? Ọlọ́run ń ṣọ́ wá. Kò ní kùnà láti mú ìdájọ́ òdodo wá tàbí kó fún wa ní ìbùkún ayérayé nítorí ìgbọràn wa.

Ìwé mímọ́

Nípa Ìpèsè yìí

Worship: A Study in Psalms

Àwọn sáàmù jẹ́ àkójọpọ̀ àwọn ewì àti àwọn orin tí a kọ ní ìkọjá ẹgbẹ̀rún ọdún sẹ́yìn. Bí àwọn Sáàmú ṣe ní àwọn ìyìn aláyọ̀ àti àwọn ìbànújẹ́ ọkàn, gbogbo ìwé náà jẹ́rìí sí ìfẹ́ ìdúróṣinṣin ti Ọlọ́run ní sí àwọn ènìyàn Rẹ̀ ní gbogbo ọ̀nà. Gẹ́gẹ́ bí ìwé tí ó wá ní agbedeméjì ìjọsìn Májẹ̀mú Láíláí, sáàmù kọ̀ọ̀kan ní ìrètí láti yọrí sí ìyìn Ọlọ́run nínú ikú àti àjínde Jésù Kristi.

More

Ó wù wá láti dúpẹ lọ́wọ́ ilé ìjọsìn onítẹ̀bọmi L. Camden kejì tí ó wà ní òpópónà Tọ́másì Tommy fún ìpèsè ẹ̀kọ́ yì i. Fún àlàyé ní kíkún sí i. jọ̀wọ́ kàn sí: http://www.trbc.org