Ìyìn: Àṣàrò nínú Orin DáfídìÀpẹrẹ

Kíni ó sọ?
Ásááfù kọ orin nípa bí Ọlọ́run ṣe gba Ísráẹ́lí ní oko ẹrú ní Íjíbítì. Ọlọ́run pa àṣẹ pé wọn kò gbọdọ̀ ní ọlọ́run mìráàn, ṣùgbọ́n wọ́n kọ̀ láti jọ̀wọ́ ara wọn fún Un.
Kíni ó túmọ̀ sì?
Ásááfù ké sí Ísráẹ́lí láti péjọ ní Jerúsálẹ̀mù fún àsè àti láti ṣe àjọyọ̀ dídára Olúwa sí wọn láti àtẹ̀yìnwá. Àtunbọ̀tán àìgbọràn wọn yára bo ayọ̀ ìrántí ìdáǹdè àwọn baba-ńlá wọn ní Íjíbítì mọ́'lẹ̀. Ọlọ́run gbà wọn láàyè láti rìn ní ọ̀nà ara wọn nígbàtí wọn kò fi etí silẹ. Gẹ́gẹ́ bí àbájáde, wọ́n kùnà látí gbé ní abẹ́ ìbùkùn àti ààbò Rẹ̀. Àsè náà jẹ́ ti àkókò àṣàrò gidigidi. Ó ṣe ni láànú pé Ísráẹ́lì wo ẹ̀yìn wọn sì kó àbámọ́, ṣùgbọ́n òtítọ́ Ọlọ́run kò ní òpin. Ó ṣì ní ìfẹ́ láti bùkùn Ísráẹ́lì kí Ó sì fún wọ́n ní ìṣẹ́gun – bí wọn bà lé tẹ́ etí sílẹ̀ kí wọ́n sì gbọ́ràn nìkan.
Báwo ni kí ń ṣe dáhùn?
Títẹ̀lé ìfẹ́ Ọlọ́run kìí ṣe ohun tí ó rọhùn ní ọ̀pọ̀ ìgbà, ṣùgbọ́n ó jẹ́ ohun tí ó yẹ láti ṣe. Ní àkọ́bẹ̀rẹ̀, o lè má rí bí Ó ṣe fẹ́ lo ọ̀nà yẹn fún nkan ti o dara rárá. Ṣùgbọ́n títẹ̀ sí ọ̀nà ara ẹni nìkan àbámọ̀ ni ó ǹ yọrí sí, ìgbé ayé àbámọ̀ sì jẹ́ ohun tí ó burú jáì. Ṣé o ti pàdánù àwọn àǹfààní tí Ọlọ́run fún ọ láti bùkùn ọ àti láti dáàbò bó ọ́ nítorípé o ṣe orí kunkun láti gbọ́ràn sì Òun? Kini awọn ǹkan wo nínú ayé rẹ tí ó mú ewu bá ọ tàbí èyí ti o lè tún mú ewu wá sínú ayé rẹ lẹ́ẹ̀kan sii? Ṣe ìpinnu láti gbé lòní nínú ìmòye pé ó wá níwájú Ọlọ́run àti ìtọ́ni Rẹ̀. Kí o wá wo ẹ̀yìn wo lòní wípé kò sì àbámọ̀ kankan.
Ìwé mímọ́
Nípa Ìpèsè yìí

Àwọn sáàmù jẹ́ àkójọpọ̀ àwọn ewì àti àwọn orin tí a kọ ní ìkọjá ẹgbẹ̀rún ọdún sẹ́yìn. Bí àwọn Sáàmú ṣe ní àwọn ìyìn aláyọ̀ àti àwọn ìbànújẹ́ ọkàn, gbogbo ìwé náà jẹ́rìí sí ìfẹ́ ìdúróṣinṣin ti Ọlọ́run ní sí àwọn ènìyàn Rẹ̀ ní gbogbo ọ̀nà. Gẹ́gẹ́ bí ìwé tí ó wá ní agbedeméjì ìjọsìn Májẹ̀mú Láíláí, sáàmù kọ̀ọ̀kan ní ìrètí láti yọrí sí ìyìn Ọlọ́run nínú ikú àti àjínde Jésù Kristi.
More