Ìyìn: Àṣàrò nínú Orin DáfídìÀpẹrẹ

Worship: A Study in Psalms

Ọjọ́ 56 nínú 106

Kí ni ó sọ?

Ọba yóò ṣe ìdájọ́ àwọn ènìyàn, yóò dáàbò bo àwọn tí à ń pọ́n ní ojú, yóò ṣe àkóso àwọn orílẹ̀-èdè, yóò dá àwọn aláìní nídè, yóò sì gba àwọn tí a ń ni lára ​​là.

Kí ni ìtúmọ̀ rẹ̀?

A rò pé Dáfídì kọ sáàmù yìí gẹ́gẹ́ bíi àdúrà kan fún Sólómọ́nì, ọba ọjọ́ iwájú Ísírẹ́lì. Ó bèèrè pé kí Ọlọ́run bùkún ọmọ rẹ̀ àti ìjọba náà pẹ̀lú òtítọ́ àti ìdájọ́ òdodo. Àwọn àbùdá tí ó wà nínú àdúrà Dáfídì ṣe àpèjúwe olùṣàkóso aláàánú tí yóò mú ààbò àti ìṣerere wá sí ìjọba náà àti gbogbo ayé. Irú ìṣèlú àti ìjọba yìí yóò bu ọlá fún Olúwa yóò sì já sí ìyìn fun Ọlọ́run. Bí Sọ́lómọ́nì ṣe di ọlọ́gbọ́n àti ọlọ́rọ̀ tó, kò kún ojú òsùnwọ̀n irú aṣíwájú tí ó dára jùlọ́ tí a ṣe àpèjúwe rẹ̀ nínú àdúrà bàbá rẹ̀. Ọmọ Dáfídì tí ó ga jù lọ nìkan, Jésù, ni yóò mú àsọtẹ́lẹ̀ nípa Ọba olótìítọ́ àti olódodo tí Ọlọ́run ti yàn ṣẹ. Nígbà tí Jésù kọ́kọ́ wá, Ó ṣe ìtọ́jú àwọn tálákà, àwọn aláìní, àti àwọn tí à ń ni lára. Yóó padá wà láti wá tú àwọn tí ó ń tẹ̀lé E sílẹ̀ yóò sì jọba lórí ayé, èyí tí yóò mú kí gbogbo orílẹ̀ èdè kí ó yin orúkọ Rẹ̀ lógo,.

Báwo ni kí n ṣe dáhùn?

Ọ̀nà wo ni o ti fi ní ìrírí àánú Krístì? Ṣé Ó ti fi àánú hàn ọ́ nígbà tí o wà nínú àìní tàbí ṣé ó ti gbèjà rẹ nígbà tí o wà ní ipò àìlera? Jésù ń tọ̀ wá wá pẹ̀lú inú rere àti àánú, ó lè gbà wá là kí ó sì tún tì wá lẹ́hìn. Tí a bá ti rí inú rere gbà lọ́dọ̀ Rẹ̀, ó yẹ kí àwa náà ṣe àfihàn rẹ̀. Àwọn ènìyàn péréte ni yóò kọ ẹ̀hìn sí pé kí wọ́n ṣe wọ́n ní àánú. Báwo ni o ṣe lè ran ẹnìkan lọ́wọ́ nínú ọ̀sẹ̀ yí? Ohunkóhun tí a bá lè ṣe, ó yẹ kí á ṣe é. Lónìí, sinmi lé òdodo Ọba wa kí o sì fi àánú Rẹ̀ hàn sí ẹnìkan.

Ìwé mímọ́

Nípa Ìpèsè yìí

Worship: A Study in Psalms

Àwọn sáàmù jẹ́ àkójọpọ̀ àwọn ewì àti àwọn orin tí a kọ ní ìkọjá ẹgbẹ̀rún ọdún sẹ́yìn. Bí àwọn Sáàmú ṣe ní àwọn ìyìn aláyọ̀ àti àwọn ìbànújẹ́ ọkàn, gbogbo ìwé náà jẹ́rìí sí ìfẹ́ ìdúróṣinṣin ti Ọlọ́run ní sí àwọn ènìyàn Rẹ̀ ní gbogbo ọ̀nà. Gẹ́gẹ́ bí ìwé tí ó wá ní agbedeméjì ìjọsìn Májẹ̀mú Láíláí, sáàmù kọ̀ọ̀kan ní ìrètí láti yọrí sí ìyìn Ọlọ́run nínú ikú àti àjínde Jésù Kristi.

More

Ó wù wá láti dúpẹ lọ́wọ́ ilé ìjọsìn onítẹ̀bọmi L. Camden kejì tí ó wà ní òpópónà Tọ́másì Tommy fún ìpèsè ẹ̀kọ́ yì i. Fún àlàyé ní kíkún sí i. jọ̀wọ́ kàn sí: http://www.trbc.org