Ìyìn: Àṣàrò nínú Orin DáfídìÀpẹrẹ

Worship: A Study in Psalms

Ọjọ́ 61 nínú 106

Kíni o sọ?

Ásáfù bẹ Ọlọ́run pé kí Ó ṣàánú kí Ó sì dáríjì Ísírẹ́lì nítori ògo orúko Rẹ̀. Ó bẹ Olúwa pé kí Ó padà sọ́dọ̀ àwọn ènìyàn Rẹ̀ kí á lè jí wọn dìde kí a sì dá wọn padà.

Kí ló túmọ̀ sí?

Wọ́n máa ń kọ Sáàmù 79 ní àkókò òjò ní gbà àjọ Ìrékọjá, wọ́n si máà ń kọ Sáàmù 80 ní ìgbà ẹ̀rùn nígbà ayẹyẹ àwon Àgó. Àwon Sáàmù méjìjí yìí ó sọ nípa bí a ṣe pa Jerúsálẹ́mù run tí a sì sọ tẹ́ńpìlì Olúwa di ẹlẹ́gbin, ó ṣeéṣe kí èyí má a sọ nípa bí àwọn ará Bábílónì ṣe gbógun ti àwọn ènìyàn Ọlọ́run tí wọ́n sì kó wọn nígbèkùn. Àwọn sáàmù wọ̀nyí jẹ́ ìránnilétí ọdọọdún pé Ọlọ́run kì í jẹ́ kí ẹ̀ṣẹ̀ kọjá láí kíyè sí i; ó ní àbájáde búburú lórí ilẹ̀ wọn, àwọn ènìyàn wọn, àti ìjọsìn wọn. Ní àsẹ̀yìnwá àsẹ̀yìnbọ̀, àtúntò Ísírẹ́lì yóò wá nípasẹ̀ ọkùnrin tí Ọlọ́run gbé dìde – Mèsáyà náà, Jésù Kristi. Òun nìkan ló lè gba àwọn tó bá ń ké pe orúkọ Rẹ̀ là.

Báwo ni kí n ṣe dáhùn?

A ti fojú kékeré wo ẹ̀ṣẹ̀ débi pé ó ṣòro fún wa láti mọ bí ẹ̀ṣẹ̀ ṣe ń ba orílẹ̀-èdè jẹ́ tó sì ń ba àwa fúnra wa jẹ́. Àwọn fíìmù àti ètò orí tẹlifíṣọ̀n máa ń gbé ohun tí Ọlọ́run dá lẹ́bi lárugẹ, wọ́n sì máa ń mú kó dà bí ohun tó ń panilẹ̀rín. Àmọ́ ṣá o, ẹ̀ṣẹ̀ kì í ṣe ohun àfitayín. Àwọn ẹ̀ṣẹ̀ ayé ló gba ẹ̀mí Jésù. Dúró báyìí ná kí o sì ronú sí bí ìkìlọ̀ tó wà nínú àyọkà ti ọní ṣe yẹ kó nípa lórí ìgbésí ayé rẹ. Ǹjẹ́ ẹ̀rí ọkàn rẹ ti di èyí tí kì í jẹ́ kó o ronú mọ́ nípa àwọn ẹ̀ṣẹ̀ tí ó jẹ́ ìtẹ́wọ́gbà láwùjọ? Rántí pé, bí Sátánì bá lè mú kí o pa ọ́ ní ẹ̀rín, ó lè mú kí o máa gbé nínú rẹ̀. Ṣé ìwọ yóò gbàdúrà fún àjíǹde ara ẹni àti ti orílẹ̀-èdè lónìí bí?

Nípa Ìpèsè yìí

Worship: A Study in Psalms

Àwọn sáàmù jẹ́ àkójọpọ̀ àwọn ewì àti àwọn orin tí a kọ ní ìkọjá ẹgbẹ̀rún ọdún sẹ́yìn. Bí àwọn Sáàmú ṣe ní àwọn ìyìn aláyọ̀ àti àwọn ìbànújẹ́ ọkàn, gbogbo ìwé náà jẹ́rìí sí ìfẹ́ ìdúróṣinṣin ti Ọlọ́run ní sí àwọn ènìyàn Rẹ̀ ní gbogbo ọ̀nà. Gẹ́gẹ́ bí ìwé tí ó wá ní agbedeméjì ìjọsìn Májẹ̀mú Láíláí, sáàmù kọ̀ọ̀kan ní ìrètí láti yọrí sí ìyìn Ọlọ́run nínú ikú àti àjínde Jésù Kristi.

More

Ó wù wá láti dúpẹ lọ́wọ́ ilé ìjọsìn onítẹ̀bọmi L. Camden kejì tí ó wà ní òpópónà Tọ́másì Tommy fún ìpèsè ẹ̀kọ́ yì i. Fún àlàyé ní kíkún sí i. jọ̀wọ́ kàn sí: http://www.trbc.org