Ìyìn: Àṣàrò nínú Orin DáfídìÀpẹrẹ

Worship: A Study in Psalms

Ọjọ́ 59 nínú 106

Kí ni ó sọ?

Ásáfù ṣe àlàyé nípa títóbi Ọlọ́run, Ẹni tí ó gba Ísrẹ́lì là l'ọwọ àwọn ọtá rẹ̀. Ó rántí ohun tí Olúwa ti ṣe ní ayé wọn, ó sì béèrè fún àánú ní ẹ̀ẹ̀kan si fún Ísrẹ́lì.

Kí ni ó tumọ̀ sí?

Yálà ní àkókò tí ó wọ̀ tàbí àkókò tí kò wọ̀, Ásáfù gba àdúrà sí Ọlọ́run, ó ń yìn-Ín fún iṣẹ́ àti ìṣesí Rẹ̀. Nínú Sáàmù 76, Ásáfù ṣe ayẹyẹ títóbi Ọlọ́run 'ẹ́yìn ìparun ọmọ ogún ọ̀tá, tí ó dàbí ìṣẹ́gun àwọn Asíríà nínú èyí tí ọmọ Ísrẹ́lì kánkán kò gbé idà sókè rárá (2 Kró. 32:16-23). Nínú Sáàmù 77, Ásáfù ní ìmọ̀lára wí pé Olúwa tí gbàgbé wọ́n pátápátá. Ní alẹ ọjọ́ kan tí kò rí orun sùn, èrò ọkàn rẹ̀ lọ sí ìdáǹdè tí wọ́n ní l'áti ọwọ́ Ọlọ́run s'ẹ́yìn. Ó gbé ọkàn rẹ̀ kúrò nínú ìpọ́njú tí wọ́n wà ó sì gbé ọkàn lé Ọlọ́run tí Ó ń fún wọn ní ìtùnú. Àwọn ipò tí ó wà ti yí padà ṣùgbọ́n Ọlọ́run rẹ̀ kò yí padà.

Báwo ni kí n ṣe dáhùn?

Àwọn Sáàmù òní ṣe àfihàn ìrírí ayé - gbogbo ènìyàn ni ó ní ìrírí ìgbéga àti ìrẹ̀sílẹ̀. Ìgbé ayé a dá bíi olóbìrípo tí ìwòye wa bá ní àsopọ̀ pẹ̀lú ẹ̀dùn ọkàn wa. Ní ìgbà tí ó bá dà bí ohun gbogbo ní àyíká wa ń yí bíríbírí, Jésù jẹ́ Ẹni tí kò yí padà rí tí Ó sì dá bíi ìdákọ̀ró fún ẹ̀mí wá. Ǹjẹ́ o ní ìrírí àkókò tí ó dára àti àwọn ọjọ́ tí ó wá ní ìdákẹ́-rọrọ nísinsìnyí bí? Gba àdúrà ní'gbà náà kí o sì yin Olúwa l'ógo. Ṣé ò ń la òkùnkùn, alẹ́ àìrórunsùn kọjá bí? Gba àdúrà ní'gbà náà kí o sì jẹ́ kí Ọlọ́run fi ara hàn ọ́, kí o jẹ́ kí ìpèsè àtẹ̀hìnwá jẹ́ ìtura fún ọkàn àti ara rẹ̀. Ó ti ṣe bẹ́ẹ̀ tẹ́lẹ̀ rí, Ó sì tún lè ṣe bẹ́ẹ̀ ní ẹ̀ẹ̀kan si. Yin Olúwa l'ógo!

Nípa Ìpèsè yìí

Worship: A Study in Psalms

Àwọn sáàmù jẹ́ àkójọpọ̀ àwọn ewì àti àwọn orin tí a kọ ní ìkọjá ẹgbẹ̀rún ọdún sẹ́yìn. Bí àwọn Sáàmú ṣe ní àwọn ìyìn aláyọ̀ àti àwọn ìbànújẹ́ ọkàn, gbogbo ìwé náà jẹ́rìí sí ìfẹ́ ìdúróṣinṣin ti Ọlọ́run ní sí àwọn ènìyàn Rẹ̀ ní gbogbo ọ̀nà. Gẹ́gẹ́ bí ìwé tí ó wá ní agbedeméjì ìjọsìn Májẹ̀mú Láíláí, sáàmù kọ̀ọ̀kan ní ìrètí láti yọrí sí ìyìn Ọlọ́run nínú ikú àti àjínde Jésù Kristi.

More

Ó wù wá láti dúpẹ lọ́wọ́ ilé ìjọsìn onítẹ̀bọmi L. Camden kejì tí ó wà ní òpópónà Tọ́másì Tommy fún ìpèsè ẹ̀kọ́ yì i. Fún àlàyé ní kíkún sí i. jọ̀wọ́ kàn sí: http://www.trbc.org