O. Daf 73:1-28

O. Daf 73:1-28 YBCV

NITÕTỌ Ọlọrun ṣeun fun Israeli, fun iru awọn ti iṣe alaiya mimọ́. Ṣugbọn bi o ṣe ti emi ni, ẹsẹ mi fẹrẹ yẹ̀ tan; ìrin mi fẹrẹ yọ́ tan. Nitori ti emi ṣe ilara si awọn aṣe-fefe, nigbati mo ri alafia awọn enia buburu. Nitoriti kò si irora ninu ikú wọn: agbara wọn si pọ̀. Nwọn kò ni ipin ninu iyọnu enia; bẹ̃ni a kò si wahala wọn pẹlu ẹlomiran. Nitorina ni igberaga ṣe ká wọn lọrun bi ẹ̀wọn ọṣọ́; ìwa-ipa bò wọn mọlẹ bi aṣọ. Oju wọn yọ jade fun isanra: nwọn ní jù bi ọkàn wọn ti nfẹ lọ. Nwọn nṣẹsin, nwọn si nsọ̀rọ buburu niti inilara: nwọn nsọ̀rọ lati ibi giga. Nwọn gbé ẹnu wọn le ọrun, ahọn wọn si nrìn ilẹ já. Nitorina li awọn enia rẹ̀ ṣe yipada si ihin: ọ̀pọlọpọ omi li a si npọn jade fun wọn. Nwọn si wipe, Ọlọrun ti ṣe mọ̀? ìmọ ha wà ninu Ọga-ogo? Kiyesi i, awọn wọnyi li alaìwa-bi-ọlọrun, ẹniti aiye nsan, nwọn npọ̀ li ọrọ̀. Nitõtọ li asan ni mo wẹ̀ aiya mi mọ́, ti mo si wẹ̀ ọwọ mi li ailẹ̀ṣẹ. Nitoripe ni gbogbo ọjọ li a nyọ mi lẹnu, a si nnà mi li orowurọ. Bi emi ba pe, emi o fọ̀ bayi: kiyesi i, emi o ṣẹ̀ si iran awọn ọmọ rẹ. Nigbati mo rò lati mọ̀ eyi, o ṣoro li oju mi. Titi mo fi lọ sinu ibi-mimọ́ Ọlọrun; nigbana ni mo mọ̀ igbẹhin wọn. Nitõtọ iwọ gbé wọn ka ibi yiyọ́: iwọ tì wọn ṣubu sinu iparun. Bawo li a ti mu wọn lọ sinu idahoro yi, bi ẹnipe ni iṣẹju kan! ibẹru li a fi nrun wọn patapata. Bi igbati ẹnikan ba ji li oju alá; bẹ̃ni Oluwa, nigbati iwọ ba ji, iwọ o ṣe àbuku àworan wọn. Bayi ni inu mi bajẹ, ẹgún si gun mi li ọkàn mi. Bẹ̃ni mo ṣiwere, ti emi kò si mọ̀ nkan; mo dabi ẹranko niwaju rẹ. Ṣugbọn emi wà pẹlu rẹ nigbagbogbo: iwọ li o ti di ọwọ ọtún mi mu. Iwọ o fi ìmọ rẹ tọ́ mi li ọ̀na, ati nigbẹhin iwọ o gbà mi sinu ogo. Tani mo ni li ọrun bikoṣe iwọ? kò si si ohun ti mo fẹ li aiye pẹlu rẹ. Ẹran-ara mi ati aiya mi di ãrẹ̀ tan: ṣugbọn Ọlọrun ni apata aiya mi, ati ipin mi lailai. Sa wò o, awọn ti o jina si ọ yio ṣegbe: iwọ ti pa gbogbo wọn run ti nṣe àgbere kiri kuro lọdọ rẹ. Ṣugbọn o dara fun mi lati sunmọ Ọlọrun: emi ti gbẹkẹ mi le Oluwa Ọlọrun, ki emi ki o le ma sọ̀rọ iṣẹ rẹ gbogbo.