Ìyìn: Àṣàrò nínú Orin DáfídìÀpẹrẹ

Worship: A Study in Psalms

Ọjọ́ 58 nínú 106

Kí ni ó sọ?

Ásáfù pohùnréré ẹkùn lórí ipò ìbànújẹ́ tí Jerúsálẹ́mù wà. Ó sọ àwọn ohun tí Ọlọ́run ti ṣe sẹ́yìn ó sì ké pè É láti gba àwọn ènìyàn Rẹ̀ sílẹ̀.

Kí ni ó túmọ̀ sí?

Ásáfù wà ní idààmú okàn. Ìkọlù ti dé bá Jerúsálẹ́mù, wọ́n sì ti wó tẹ́mpílì palẹ̀. Ó dàbí Ọlọ́run tí kọ̀ àwọn ènìyàn Rẹ̀ sílẹ̀. Kò bá àwọn ènìyàn Rẹ̀ sọ̀rọ̀ tí ó fanimọ́ra mọ́ gẹ́gẹ́ bíi Olùsọ́àgùntàn wọn, ṣùgbọ́n Ó gba ọwọ́ líle láyè láti ọ̀dọ̀ ọ̀tá wá gẹ́gẹ́ bíi ìdájọ́ Rẹ̀ fún ẹ̀ṣẹ̀ wọn. Síbẹ̀síbẹ̀ Ásáfù sì gbẹ́kẹ̀lé Ọlọ́run, ó sì ní ìdánilójú pé Olúwa lè ṣeẹ́, àti pé yíò ṣeẹ́, láti sẹ́gun ọ̀tá wọn. Ọlọ́run ló ní gbogbo asẹ́ lọ́wọ́. Ó ń ṣe àkóso lórí ìṣẹ̀dá Rẹ̀. Nítorí ìdí èyí dájúdájú Ó lágbára láti gba àwọn ènìyàn Rẹ̀ sílẹ̀. Ásáfù sọ fún Ọlọ́run pé kí Ó rántí ìlérí tí Ó ṣe fún Ísírẹ́lì. Ní ìwọ̀n ìgbà tí Ọlọ́run ti ṣe ìdájọ́ ẹ̀ṣẹ̀ àwọn tí ó jẹ́ tì Rẹ, láìsí àní-àní Ó ṣe tán láti fi ìyà jẹ àwọn ọ̀tá wọn fún ìwà ibi wọn.

Báwo ni ó ṣe yẹ kí n dáhùn?

A máa sábà ní èrò pé Ọlọ́run jẹ́ Baba aláànú tàbí Olùṣọ́àgùntàn ónìrèlè, ṣùgbọ́n a kò fẹ́ dúró lórí òtítọ́ wípé Ó tún jẹ́ Adájọ́. Ọlọ́run ni ó ní òpin àṣẹ lọ́wọ́. Òun ní yíò mú kí gbogbo ènìyàn jíyìn ìṣe wọn sí Òun àti sí àwọn míràn. Ibi kíkà wá tòní fún wa ní òye àwọn ọ̀rọ̀ ìwé Hébérù 10:31: "Ohun ẹ̀rù ni láti ṣubú sí ọwọ́ Ọlọ́run alààyè!". Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé àwọn ọ̀rọ̀ wọ̀nyí mú ibẹru wá, ó yẹ kí a rántí pé àánú Ọlọ́run á máa ṣògo lórí ìdájọ́. Nígbàtí a bá gbé àánú Ọlọ́run yè wò, a óò rí ipa tí Ó kó nípa ẹ̀ṣẹ̀ wá àti ìkùnà wá, bí Ó ṣe pèsè ọmọ Rẹ̀ kan ṣoṣo fún ìrúbọ dípò wá. Ní ọjọ́ kan, Ọlọ́run yíò ṣe ìdájọ́ ayé nípa iṣẹ́ búburú ọwọ́ wọn, ṣùgbọ́n bí o bá ti ní ẹ̀bùn ìgbàlà, ìwọ kò nílò láti bẹ̀ẹ̀rù Rẹ̀ gẹ́gẹ́ bíi onídàájọ́. Ìwọ́ lè wo Ọlọ́run gẹ́gẹ́ bíi Bàbá rẹ tí mbẹ ní ọ̀run tí Ó féràn rẹ àti ọmọ Rẹ̀ gẹ́gẹ́ bíi Olùṣọ́àgùntàn onirele.

Nípa Ìpèsè yìí

Worship: A Study in Psalms

Àwọn sáàmù jẹ́ àkójọpọ̀ àwọn ewì àti àwọn orin tí a kọ ní ìkọjá ẹgbẹ̀rún ọdún sẹ́yìn. Bí àwọn Sáàmú ṣe ní àwọn ìyìn aláyọ̀ àti àwọn ìbànújẹ́ ọkàn, gbogbo ìwé náà jẹ́rìí sí ìfẹ́ ìdúróṣinṣin ti Ọlọ́run ní sí àwọn ènìyàn Rẹ̀ ní gbogbo ọ̀nà. Gẹ́gẹ́ bí ìwé tí ó wá ní agbedeméjì ìjọsìn Májẹ̀mú Láíláí, sáàmù kọ̀ọ̀kan ní ìrètí láti yọrí sí ìyìn Ọlọ́run nínú ikú àti àjínde Jésù Kristi.

More

Ó wù wá láti dúpẹ lọ́wọ́ ilé ìjọsìn onítẹ̀bọmi L. Camden kejì tí ó wà ní òpópónà Tọ́másì Tommy fún ìpèsè ẹ̀kọ́ yì i. Fún àlàyé ní kíkún sí i. jọ̀wọ́ kàn sí: http://www.trbc.org