Ìyìn: Àṣàrò nínú Orin DáfídìÀpẹrẹ

Kíni ó sọ?
Ásáfù tẹnu mọ́ bí kíkọ́ àwọn ìran tí ń bọ̀ nípa Olúwa ṣe ṣe pàtàkì.
Kíni ìtumọ̀ rẹ̀?
Eyi jẹ psalmu ti o tan ìmọlẹ tabi tí o tọni sona. Ìtọ́ni onísáàmù náà ni pé kí ó kẹ́kọ̀ọ́ láti inú ohun tí ó ti kọjá, kí ó sì fún àwọn ẹlòmíràn ní ìtọ́ni. Ìran kọ̀ọ̀kan ló ní ojúṣe láti kọ́ àwọn ọmọ wọn ní ohun tí wọ́n ti kọ́ nípa Olúwa. Àwọn ọmọdé tí a kọ́ láti mọ ipa ọwọ́ Ọlọ́run bí Ó ṣe ń ṣiṣẹ́ ní àgbáyé ń kọ́ ẹ̀kọ́ láti gbẹ́kẹ̀lé agbára Rẹ̀. Lọ́pọ̀ ìgbà, àwọn ọmọ tí a fún ní ìtọ́ni nínú Òfin Rẹ̀ máa tẹ̀lé àwọn àṣẹ Rẹ̀. Bí a kò bá tẹ àwọn òtítọ́ wọ̀nyí mọ́ àwọn ọmọdé lára láti kékeré, wọ́n á tẹ̀ lé ìwà ẹ̀ṣẹ̀ wọn, wọn yóò gbàgbé nípa ohun tí Ọlọ́run ti ṣe, wọn yóò sì kọ̀ láti ṣè ìgbọràn sí i. Láti fi ìdí ọ̀rọ̀ rẹ̀ múlẹ̀, Ásáfù sọ ìtàn nípa ọ̀pọ̀ ìgbà tí Ísírẹ́lì ti ṣọ̀tẹ̀ sí Ọlọ́run.
Báwo ni kí n ṣe dáhùn?
Gẹ́gẹ́ bíi òbí, a fi han àwọn ọmọ wẹ́wẹ́ wa láti ìgbà èwe bí wọ́n ṣe le fọ eyín wọn, a sọ fún wọn pé kí wọ́n jẹ ewébẹ̀, a fi orúkọ wọn sílẹ̀ ní orísirísi àwọn kíláàsì, a sì ń gbé wọn lọ sí àwọn ibi eré ìdárayá olọ́kanòjọ̀kan. Síbẹ̀, nínú gbogbo ohun tí àwọn òbí lè ṣe fún àwọn ọmọ wọn, kò sí ohun tó ṣe pàtàkì ju kíkọ́ wọn ní òtítọ́ nípa Ọlọ́run. Gbígbé wọn lọ sí ilè ìjọsìn tí ó gba Bíbélì dójú ṣe pàtàkì, ṣùgbọ́n àwọn òtítọ yìí gbọ́dọ̀ ní àtìlẹ́yìn tó ní iṣẹ́ pẹ̀lú ẹ̀kọ́ tí ó wúlò ní ìgbésí ayé ojoojúmọ́ àti nípa ṣíṣe àpẹẹrẹ ìgbẹ́kẹ̀lé nínú Olúwa àti ìgbọràn sí Ọ̀rọ̀ Rẹ̀. Kíni àwọn ọmọ àti àwọn ọmọ-ọmọ rẹ kọ́ nípa Olúwa nínú ọ̀rọ̀ àti ìṣesí rẹ? Ṣe àkíyèsí àwọn àkókò tí o le kọ́ won ní ẹ̀kọ́ loòní. Sọ fún wọn nípa bí Olórun ṣe ṣe itọ́jú ẹbí rẹ ní igbà tó ti kọjá sẹ́yìn. Fi ohun tí Bíbélì ṣọ nípa àwọn ohun tí wọ́n ń là kọjá ní ilé ìwé àti pẹ̀lú áwọn ọ̀rẹ́ hàn wọ́n, kí o sì gba àdúrà pẹ̀lú wọn nípa àwọn nǹkan wọ̀nyí. Bí ìwọ kò bá tẹ ìgbàgbọ́ rẹ mọ́ wọn lára, kí ó sì wà lóókan àyà wọn, wọn yíò kọ́ ẹ̀kọ́ ti ayé.
Ìwé mímọ́
Nípa Ìpèsè yìí

Àwọn sáàmù jẹ́ àkójọpọ̀ àwọn ewì àti àwọn orin tí a kọ ní ìkọjá ẹgbẹ̀rún ọdún sẹ́yìn. Bí àwọn Sáàmú ṣe ní àwọn ìyìn aláyọ̀ àti àwọn ìbànújẹ́ ọkàn, gbogbo ìwé náà jẹ́rìí sí ìfẹ́ ìdúróṣinṣin ti Ọlọ́run ní sí àwọn ènìyàn Rẹ̀ ní gbogbo ọ̀nà. Gẹ́gẹ́ bí ìwé tí ó wá ní agbedeméjì ìjọsìn Májẹ̀mú Láíláí, sáàmù kọ̀ọ̀kan ní ìrètí láti yọrí sí ìyìn Ọlọ́run nínú ikú àti àjínde Jésù Kristi.
More