Ètò Ọlọ́jọ́ Mọ́kànlélọ́gbọ̀n fún Àtúntò ÌgbéyàwóÀpẹrẹ

31 Day Marriage Reset

Ọjọ́ 12 nínú 31

Kò sí ohun tí ó lè fa ìdàrúdàpọ̀ ní inú ìgbéyàwó rẹ àyàfi tí o bá fún-un ní ààyè ju àdúrà lọ, àti àkíyèsí ju Jésù lọ. 

•••

Ó dà bíi pé ọ̀pọ̀lọpọ̀ ìgbà ni àkíyèsí tí a fi sí ìṣòro kàn ń já sí ìṣòro ńlá ju ohun tí a rò pé ó jẹ́ ìṣòro gangan. Ìgbà mélòó ni ó ti jẹ́ pé o ní ìdààmú tàbí ìgbóná ọkàn nípa nkankan, tí ó sì jẹ́ wípé àsẹ̀hìnwá àsẹ̀hìnbọ̀ ó já sí dáradára? Mo mọ̀ wípé mo ṣe èyí ní ọ̀pọ̀lọpọ̀ ìgbà. Mo ní wàhálà lórí bí a ṣe fẹ́ san owó eléyì àti tọ̀hún àti bí a ṣe ní láti dé ibi méjì ní èẹ̀kan ṣoṣo, lẹ́yìn náà ó yọrí sí dáradára. Kíni ìdí tí àwọn nkan wọ̀nyí dà bíi pé ó yọrí sí dáradára? Nitori wípé mo jẹ́ ọmọ Ọlọ́run àti wípé ní àkókò tí mò ń bẹ̀ru Ọlọ́run fi ojútùú sí i. Ó ní èrò fún ìṣòro mi! Ó ní ìdáhùn sí àìbalẹ̀ ọkàn mi. Gẹ́gẹ́ bíi àwọn ọmọ Ọlọ́run, a kò ní ìdí láti ṣe wàhálà tàbí dààmú. Gẹ́gẹ́ bíi àwọn ọmọ Aṣẹ̀dá tí ó dá àkókò fúnrarẹ̀, a lè gbẹ́kẹ̀le àkókò Rẹ̀. Gẹ́gẹ́ bíi àwọn ọmọ Ọba àwọn ọba, ìdààmú jẹ́ fífi àkókò ṣòfò. Ààbò wá fún wa. A dì wá mú. A wà ní abẹ́ ìtọ́jú. A jẹ́ àyànfẹ́. A ní Ọlọ́run Olódùmarè tí ó ní ìfẹ́ wá, ati ànfàní láti bẹ̀bẹ̀ fún wa ní èyíkéyí àyídáyidà tàbí ipò, àti láti ṣiṣẹ́ fún rere wá. Bí nkankan bá wà nínú ìgbéyàwó rẹ̀ tí kò jẹ́ kí ní ayọ̀ nínú ìgbésí ayé rẹ̀, tàbí tí nkankan bá wà nínú ìgbéyàwó rẹ tí ó jẹ́ ìdènà fún ìrètí rẹ, sọ òtítọ́ ọ̀rọ̀ Ọlọ́run lórí àwọn ńkan wọ̀nyẹn ní báyìí ní orúkọ Jésù! Kò gba àsìkò rárá! Ọlọ́run wà fún ọ! Ó ní èrò fún ọ! Ó ní ìdí pàtàkì kan fún ọ! Ó dára! Ó jẹ́ olóòtọ́! Gbẹ́kẹ̀ rẹ lé E! 

Ìwé mímọ́

Nípa Ìpèsè yìí

31 Day Marriage Reset

Ǹjẹ́ o nílò ohun tí yíò mú kí ìgbéyàwó rẹ sunwọ̀n sí i? Ẹ ka Ìwé Mímọ́, kí ẹ sì bá ara yín jíròrò fún ọjọ́ mọ́kànlélọ́gbọ̀n gbáko, ẹ ó sì rí bí Jésù yíò ṣe fi ara hàn yín!

More

A fẹ́ dúpẹ́ lọ́wọ́ ìjọ Stonecreek fún ìpèsè ètò yìí. Fún àlàyé síwájú síi, jọ̀wọ́ lọ sí: http://www.stonecreek.church