Ètò Ọlọ́jọ́ Mọ́kànlélọ́gbọ̀n fún Àtúntò ÌgbéyàwóÀpẹrẹ

Tí mo bá ti kọ́ ohun kàn nípa wíwà ní ìrẹ́pọ̀ pẹ̀lú olólùfẹ́ mi, òun ni pé Jésù n bá mí lò ní ọ̀nà ti olólùfẹ́ n fẹ́ ki n bá a lò.
•••
Olólùfẹ́ rẹ kìí ṣe ẹni pípé, àti pé ó ṣe pàtàkì fún ọ láti mọ̀ pé ìwọ náà pẹ̀lú kò pé. Ó rọrùn púpọ̀ láti gbàgbé gbogbo àwọn àkókò tí àwa ti ṣe àṣìṣe ní ìgbà tí olólùfẹ́ wa bá ṣe àṣìṣe ní ẹ̀ẹ̀kan. Ìdí nìyẹn tí ó fi ṣe pàtàkì púpọ̀ láti rántí ìdíyelé ìgbéyàwó rẹ̀ lórí ìbànújẹ́ ti ìgbà kan. Lo iṣẹ́jú kan láti rántí ọ̀nà tí Jésù gbà tọ́jú rẹ̀ ní ìgbà tí o ṣe àṣìṣe. Kò ṣe ìjayá tàbí ṣe jàmbá tàbí kígbe lè ọ lórí. Ṣe ni Ó tọ́ka rẹ padà sí Àgbélébùú ó sì rán ọ létí pé Òun ní ìfẹ́ rẹ̀ síbẹ̀ síi. Ó ṣe pàtàkì sí àwọn ìgbéyàwó wa láti dáríjì ara wa, láti rántí ìdáríjì tí a ti rí gbà, àti láti fi ara mọ́ àpẹẹrẹ Jésù típẹ́ típẹ́ ní ìgbà gbogbo ní ìgbà tí ó bá dé ọ̀nà tí à ń gbà tọ́jú olólùfẹ́ wa. Béèrè ní ọwọ́ Ọlọ́run fún ìtọ́sọ́nà àti oore-ọ̀fẹ́ láti ní ìfẹ́ olólùfẹ́ rẹ ní ọ̀nà tí a pè ọ́ sí. Ó fẹ́, Ó sì ní agbára láti ràn ọ́ l'ọ́wọ́ ní gbogbo ọ̀nà!
Ìwé mímọ́
Nípa Ìpèsè yìí

Ǹjẹ́ o nílò ohun tí yíò mú kí ìgbéyàwó rẹ sunwọ̀n sí i? Ẹ ka Ìwé Mímọ́, kí ẹ sì bá ara yín jíròrò fún ọjọ́ mọ́kànlélọ́gbọ̀n gbáko, ẹ ó sì rí bí Jésù yíò ṣe fi ara hàn yín!
More