Ètò Ọlọ́jọ́ Mọ́kànlélọ́gbọ̀n fún Àtúntò ÌgbéyàwóÀpẹrẹ

Jẹ́ ẹnìkan tí olólùfẹ́ rẹ̀ lè gbójú lè àti fi ọkàn tán.
•••
Ọ̀nà kan tí o lè ṣe àfihàn Ọlọ́run nínú ìgbéyàwó rẹ̀ ni láti mú àwọn ìlérí rẹ ṣẹ. Ọlọ̀run kìí yẹ àwọn ìlérí rẹ nítorí ìhùwàsí rẹ àti pé kò yẹ kí ìwọ náà ṣe aláìmú tirẹ sẹ nítorí ìhùwàsí olólùfẹ́ rẹ. Kọjú sí Ọlọ́run kí o bẹ̀ Ẹ́ láti ràn ọ́ l'ọ́wọ́ láti jẹ́ olólùfẹ́ tí ó bu ọlá fún ìlérí nínú ìgbéyàwó àti láti pa ọ́ mọ́ l'ọ́wọ́ irọ́kírọ́ tí Sátánì bá gbìyànjú láti sọ fún ọ. Sátánì yíò gbìyànjú ní ìgbà gbogbo láti fà ọ́ kúrò ní orí àwọn ìlérí tí o sọ ní ọjọ́ ìgbéyàwó rẹ ní ìgbà tí ọjọ́ “búburú” bá dé, ṣùgbọ́n rántí pé ní ọjọ́ náà o sọ pé, “ní ìgbà tí ó dára tàbí burú”. Pinnu láti fi han olólùfẹ́ rẹ pé o dúró lórí ìlérí rẹ.
Ìwé mímọ́
Nípa Ìpèsè yìí

Ǹjẹ́ o nílò ohun tí yíò mú kí ìgbéyàwó rẹ sunwọ̀n sí i? Ẹ ka Ìwé Mímọ́, kí ẹ sì bá ara yín jíròrò fún ọjọ́ mọ́kànlélọ́gbọ̀n gbáko, ẹ ó sì rí bí Jésù yíò ṣe fi ara hàn yín!
More