Ètò Ọlọ́jọ́ Mọ́kànlélọ́gbọ̀n fún Àtúntò ÌgbéyàwóÀpẹrẹ

Ohun tí ó dára jù lọ tí mo lè ṣe fún ìgbéyàwó mi ni láti fi Ọlọ́run àti Ọ̀rọ̀ Rẹ̀ ṣe àfojúsùn mi.
•••
Mo ka àfiwé kan ní àkókò kan tí ó sọ nípa bí ó ṣe jẹ́ ohun tí ó wà ní inú ènìyàn ní yíò jáde. Wọn ṣe àlàyé rẹ nípa lílo ife kọfí. Wọn bẹ̀rẹ̀ pẹ̀lú ìbéèrè yí, “Tí o bá gbé ife tí ó kún fún kọfí lọ́wọ́ tí enìkan kọ̀ lú ọ tí kọfí ọwọ́ rẹ sì dànù — Kí ni ìdí tí ó fi jẹ́ kọfí ni ó dànù?” Ìdáhùn rẹ̀ ni pé kọfí ni ó dànù nítorí pé kọfí ni ó wà ní inú ife rẹ. Tí ó bá jẹ́ ṣokolétí gbígbóná ní, ohun náà ni yíò yí dànù. Ohunkóhun tí ó bá wà ní inú ife ni yíò yí dànù. Àfiwé náà parí pẹ̀lú ìbéèrè yí, “Nítorí náà tí ayé bá mì ọ́ — Kí ni ohun tí yíò yí dànù? Kí ni ó wà ní inú ife rẹ?” Èyí jẹ́ àfiwé tí ó dára. Tí o bá ń kún ife rẹ ní ìgbà gbogbo pẹ̀lú àwọn ohun tí ó dára àti àwọn ohun bíi ti Ọlọ́run, tí o bá tẹra mọ̀ gbígba Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run sí inu ètò ayé rẹ, ìgbéyàwó rẹ yíò dúró lórí ilẹ̀ ṣin ṣin. Nítorí àwọn ńkan wọ̀n yẹn ní yíò jẹ yọ ní ìgbà tí ìjì bá mì ọ́.
Nípa Ìpèsè yìí

Ǹjẹ́ o nílò ohun tí yíò mú kí ìgbéyàwó rẹ sunwọ̀n sí i? Ẹ ka Ìwé Mímọ́, kí ẹ sì bá ara yín jíròrò fún ọjọ́ mọ́kànlélọ́gbọ̀n gbáko, ẹ ó sì rí bí Jésù yíò ṣe fi ara hàn yín!
More