Ètò Ọlọ́jọ́ Mọ́kànlélọ́gbọ̀n fún Àtúntò ÌgbéyàwóÀpẹrẹ

31 Day Marriage Reset

Ọjọ́ 10 nínú 31

Ní ìgbà tí o bá ṣe ìpalára fún olólùfẹ́ rẹ, o ṣe ìpalára fún Kristi náà pẹ̀lú.

•••

Ronú nípa ẹnìkan tí ó ní ìfẹ́ si láì ní ìdí. Báwo ní yíò ṣe rí ní ara rẹ tí ẹnìkan bá hù ìwà burúkú sì í tàbí kí ó kanra mọ ọn? Inú rẹ kò dùn sí, àbí? Ó ṣeé ṣe kí ó pa ìwọ náà lára pẹ̀lú, àbí? Ǹjẹ́ o mọ̀ pé bí ó ṣe rí ní ara Ọlọ́run gangan nìyẹn nípa olólùfẹ́ rẹ? Ọmọ Rẹ̀ ni ò ń bá ṣe pọ̀, àti pé ó jẹ́ ìpalára fún Un ní ìwọ̀n ìgbà tí ó bá ṣe ìpalára sí àwọn ọmọ Rẹ̀ tàbí ṣe ohun tí kò dára sí wọn. Ìyẹn jẹ́ irú ìgbọ̀wọ́ ìṣirò nlá tí ó tóbi ní inú ìgbéyàwó wa, gẹ́gẹ́ bíi ẹnì kọ̀ọ̀kan. Mo ní ìfẹ́ Ọlọ́run púpọ̀ dé ibi pé ó mú mi ní ìfẹ́ àti ìbọ̀wọ̀ fún olólùfẹ́ mi  ní ìgbà tí ó jẹ́ ohun tí mo yàn tí mo sì ní láti ṣe dípò èyí tí ó ti jẹ́ bárakú fún mi. Tí ọ̀nà tí o gbà ní ìfẹ́ Ọlọ́run kò bá yí ọ̀nà tí o gbà fẹ́ràn olólùfẹ́ rẹ padà, ìyàlẹ́nu ni yíò jẹ́ fún mi bí o bá ní ìfẹ èyíkéyìí nínú àwọn méjèèjì rárá. Bẹ Ọlọ̀run láti rán ọ l'ọwọ láti ṣe àfihàn ìfẹ́ sí olólùfẹ́ rẹ ní ìbọ̀wọ̀ fún ìfẹ́ tí o ní sí I.

Ìwé mímọ́

Nípa Ìpèsè yìí

31 Day Marriage Reset

Ǹjẹ́ o nílò ohun tí yíò mú kí ìgbéyàwó rẹ sunwọ̀n sí i? Ẹ ka Ìwé Mímọ́, kí ẹ sì bá ara yín jíròrò fún ọjọ́ mọ́kànlélọ́gbọ̀n gbáko, ẹ ó sì rí bí Jésù yíò ṣe fi ara hàn yín!

More

A fẹ́ dúpẹ́ lọ́wọ́ ìjọ Stonecreek fún ìpèsè ètò yìí. Fún àlàyé síwájú síi, jọ̀wọ́ lọ sí: http://www.stonecreek.church