Ètò Ọlọ́jọ́ Mọ́kànlélọ́gbọ̀n fún Àtúntò ÌgbéyàwóÀpẹrẹ

31 Day Marriage Reset

Ọjọ́ 22 nínú 31

Kí o tó fi àkókò ṣòfò lórí èdè àìyedè àti àìgbọ̀ráẹniyé — fi ara balẹ̀ láti kọ́ òye àti ìbáraẹnisọ̀rọ̀.

•••

Ó rọrùn láti jìn sí kòtò àìgbọ́raẹniyé. A ti ṣe eléyì ní ọ̀pọ̀lọpọ̀ ìgbà. O máa ń bínú sí nnkan kan tí a sọ tàbí tí a ṣe nítorí pé o kò fi ara balẹ̀ kí ó yé ọ. Eléyìí máa ń ṣẹlẹ̀ sí wa ní ìgbà tí ọmọ wá wà ní ìkókó. A máa ń gbìyànjú láti tọ́ ara wa sí ọ̀à ṣáá ni lóri bí ó ṣe tọ́ láti tọ́jú rẹ̀ kí ó tó di pé ìyè wa ṣí síi pé à ń pa ìgbéyàwó wa lára nípa ṣíṣe báyìi. Ìdàkejì rẹ̀ ni. Ó kàn ń mú wa láti inú ìbínú kan lọ sínú ìbínú mìíràn ni. Ní ìgbà tí ó rí bẹ́ẹ̀, àwa méjèèjì ní láti jíròrò lórí àkíyèsí tí a ṣe àti pé a ní láti fi òpin sí i. Òtítọ́ ibẹ̀ ni pé à ń gbìyànjú láti ran ara wa l'ọ́wọ́, ṣùgbọ́n ní àsìkò kan náà, a kò fi iyè sí pé àwa méjèèjì kò ní ìrírí jíjẹ́ òbí rí àti wípé a dìjọ ń wá ojútùú rẹ̀ ni. Lẹ́hìn tí a ti ṣe ìjíròrò yìí, a bẹ̀rẹ̀ síí ríi pé Ọlọ́run ti ń ṣe iṣẹ́ ní inú ìgbéyàwó wa sí rere. Bí ohun kan bá ń ṣẹlẹ̀ ní inú ìgbéyàwó rẹ tí ó ń fa ìbínú lẹ́hìn ìbínú, wá ààyè ní òní láti sọ̀rọ̀ nípa rẹ̀. Ó lè jẹ́ àìgbọ́raẹniyé lásán ni.

Ìwé mímọ́

Nípa Ìpèsè yìí

31 Day Marriage Reset

Ǹjẹ́ o nílò ohun tí yíò mú kí ìgbéyàwó rẹ sunwọ̀n sí i? Ẹ ka Ìwé Mímọ́, kí ẹ sì bá ara yín jíròrò fún ọjọ́ mọ́kànlélọ́gbọ̀n gbáko, ẹ ó sì rí bí Jésù yíò ṣe fi ara hàn yín!

More

A fẹ́ dúpẹ́ lọ́wọ́ ìjọ Stonecreek fún ìpèsè ètò yìí. Fún àlàyé síwájú síi, jọ̀wọ́ lọ sí: http://www.stonecreek.church