Ètò Ọlọ́jọ́ Mọ́kànlélọ́gbọ̀n fún Àtúntò ÌgbéyàwóÀpẹrẹ

31 Day Marriage Reset

Ọjọ́ 21 nínú 31

Mo lérò wípé o ti gba àdúrà fún aya tàbí ọkọ rẹ ní ọ̀pọ̀ ìgbà ju iye ìgbà tí o ti bínú sí wọn ní ọ̀sẹ̀ yí.

•••

Ní ìgbà tí ìgbésí ayé wa burú jù lọ, Jésù gba àdúrà fún wa. Ní ìgbà tí ẹ̀ṣẹ̀ wa kan Jésù mọ́ àgbélébùú, Ó bójú wo ọ̀run ó sì sọ wípé, “Baba, dárí jì wọ́n, nítorí wọ́n kò mọ ohun tí wọ́n ńṣe (Lúùkù 23:34).” Ǹjẹ́ a lè di ojú wa fún ìṣẹ́jú àáyá mẹ́wàá láti ṣe àṣàrò lórí èyí? Ẹ̀yin ará, ìtumọ̀ ìfẹ́ nìyí. Ó ní àǹfààní láti bínú, kò bá ti s'épè, kódà ó ní agbára láti sọ̀kalẹ̀ lórí àgbélébùú, àmọ́ kò ṣe bẹ́ẹ̀. Ó gba àdúrà fún wa. Kí ni ó fà á? Nítorí Ó fẹ́ràn wa. Ó ní májẹ̀mú kan pẹ̀lú wa tí ó ṣe pàtàkì sí I ju àwọn àṣàyàn wa lọ. Kò w'ẹnu àbùkù sí wa lára tàbí sọ bí a ti burú tó tàbí fi bí a ṣe s'ìwà wù sọ ọ̀rọ̀ sí wa, dípò èyí ṣe ni Ó gba àdúrà fún wa. Èyí. Àní èyí ni ìfihàn ìfẹ́ pẹ̀lú òtítọ́. Ní ìgbà tí aya tàbí ọkọ rẹ bá mú inú bí ọ, báwo ni ìwọ ti ń fèsì? Mo wòó wípé gbogbo wa ni a lè gbìyànjú láti fèsì bíi ti Jésù. Àní pẹ̀lú àdúrà. Kí Ọlọ́run kí ó ràn wá l'ọ́wọ́! Àmín!

Béèrè fun ìrànlọ́wọ́ Ọlọ́run láti hùwà bíi Jésù ní ìgbà tí ǹkan bá dojú rú. 

Ìwé mímọ́

Nípa Ìpèsè yìí

31 Day Marriage Reset

Ǹjẹ́ o nílò ohun tí yíò mú kí ìgbéyàwó rẹ sunwọ̀n sí i? Ẹ ka Ìwé Mímọ́, kí ẹ sì bá ara yín jíròrò fún ọjọ́ mọ́kànlélọ́gbọ̀n gbáko, ẹ ó sì rí bí Jésù yíò ṣe fi ara hàn yín!

More

A fẹ́ dúpẹ́ lọ́wọ́ ìjọ Stonecreek fún ìpèsè ètò yìí. Fún àlàyé síwájú síi, jọ̀wọ́ lọ sí: http://www.stonecreek.church