Ètò Ọlọ́jọ́ Mọ́kànlélọ́gbọ̀n fún Àtúntò ÌgbéyàwóÀpẹrẹ

Inú rẹ kò lè dùn nínú ìgbéyàwó rẹ àfi ìgbà tí o bá yàn láti tẹjú mọ́ Ọlọ́run dípò àwọn nnkan tí ó ń dà ọ́ láàmú.
•••
Ẹ wá gbọ́ o gbogbo yín...òtítọ́ ni pé ní ọ̀pọ̀ ìgbà ohun tí ó lòdì ni a máa ń fi ọkàn sí. Bí ọkọ tàbí ìyàwó wa ṣe sọ pé àwọn máa ṣe nnkan kan tí wọ́n sì gbàgbé. Bí wọ́n ṣe sọ wípé àwọn máa san gbèsè kan tí ó sì ti wá ní èlé lórí báyìí nítorí pé ó ti pẹ́ jù. Nnkan ń ṣẹlẹ̀, a tọ́ka àbùkù, ìdààmú bá oníkálukú. Àmọ́, sísunkún lẹ́hìn ìgbà tí wàrà ti dànù kò ní kí ilẹ̀ tí ó dà sí mọ́ kò sì yí pé wàrà dànù padà. Sísọ kí á máa fi oore ọ̀fẹ̀ hàn di àṣà, dípò kíkùn sínú, yóò jẹ́ kí àlàáfíà pọ̀ si nínú ìgbéyàwó rẹ. Kọ́ ẹ̀kọ́ láti inú àṣìṣe, ẹ ní ìbáraẹnisọ̀rọ̀ tí ó bá ṣeé ṣe, ṣùgbọ́n má gbé e lórí. Yí oju rẹ sí ọ̀dọ̀ Ọlọ́run kí o sì bẹ̀ Ẹ́ kí Ó ràn ọ́ lọ́wọ́ láti fi oore ọ̀fẹ́ hàn fún ọkọ tàbí ìyàwó rẹ lọ́nà tí Òun náà fi fi oore ọ̀fẹ́ hàn ọ́.
Ìwé mímọ́
Nípa Ìpèsè yìí

Ǹjẹ́ o nílò ohun tí yíò mú kí ìgbéyàwó rẹ sunwọ̀n sí i? Ẹ ka Ìwé Mímọ́, kí ẹ sì bá ara yín jíròrò fún ọjọ́ mọ́kànlélọ́gbọ̀n gbáko, ẹ ó sì rí bí Jésù yíò ṣe fi ara hàn yín!
More