Ètò Ọlọ́jọ́ Mọ́kànlélọ́gbọ̀n fún Àtúntò ÌgbéyàwóÀpẹrẹ

O kò lè ṣe àkóso olólùfẹ́ rẹ, nítorí náà o gbọ́dọ̀ gbáradì láti ṣe àkóso ara rẹ.
•••
A gbàgbọ́ pé ọ̀kan nínú àwọn okùnfà (tí kìí bá ṣe èyí tí ó jẹ́ olórí okùnfà) ìkọ̀sílẹ̀ jẹ́ àìní ìṣàkóso ara ẹni. Kíkọ̀ láti rìn ní ìbámu pẹ̀lú ọ̀rọ̀ Ọlọ́run, ṣùgbọ́n yíyàn kíkọsẹ̀ ní ìbámu pẹ̀lú ẹran ara. Ó jẹ́ ìmọtaraẹ̀ninìkan. Ó jẹ́ ìpinnu inú rẹ pé ìfẹ́ tìrẹ ṣe pàtàkì ju òtítọ́ Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run lọ. O kò lè ṣe ìpinnu fún olólùfẹ́ rẹ, ṣùgbọ́n o lè ṣe tìrẹ, o sì lè yàn àwọn èsì rẹ! Dínkù ìgbìyànju láti tún olólùfẹ́ rẹ ṣe, sì pinnu láti máà jẹ́ kí ìhùwàsí wọn mi ìfarajì rẹ sí Jésù. Ọ̀kan nínú àwọn ọ̀nà tí ó dára jù lọ láti ran olólùfẹ́ rẹ l'ọ́wọ́ láti ṣe àwọn ìpinnu bíi ti Ọlọ́run ni láti ṣe àwọn ìpinnu bíi ti Ọlọrun fún ara rẹ.
Ìwé mímọ́
Nípa Ìpèsè yìí

Ǹjẹ́ o nílò ohun tí yíò mú kí ìgbéyàwó rẹ sunwọ̀n sí i? Ẹ ka Ìwé Mímọ́, kí ẹ sì bá ara yín jíròrò fún ọjọ́ mọ́kànlélọ́gbọ̀n gbáko, ẹ ó sì rí bí Jésù yíò ṣe fi ara hàn yín!
More