Ètò Ọlọ́jọ́ Mọ́kànlélọ́gbọ̀n fún Àtúntò ÌgbéyàwóÀpẹrẹ

Má ṣe hùwà sí olólùfẹ́ rẹ ní ọ̀nà tí ó ń gbá hùwà sí ọ, dípò bẹ́ẹ̀ ṣe sí i ní ọ̀nà tí Ọlọ́run ń gbà ṣe sí ọ.
•••
Ṣé o fẹ́ kí ìgbéyàwó rẹ ní ẹwà? Kí ó dà bíi afẹ́fẹ́ ọ̀tun? Láti tan ìfẹ́, ayọ̀, àlááfíà, àti àánú? A gbàgbọ́ pé ọ̀nà kàn wà láti ní èyí. A gbàgbọ́ pé irú ìgbéyàwó báyìí ni ó ń jẹ yọ ní ìgbà tí ọkọ kan àti aya kan bá pinnu pé ìgbéyàwó wọn kò ní dá lórí ara wọn, ìmọ̀lára wọn, àti ohun tí wọ́n fẹ́, ṣùgbọ́n lórí ìpìlẹ̀ tí ó wà ní àáríngbùngbùn Jésù. Lórí fífi sùúrù àti ìwà pẹ̀lẹ́ Rẹ̀ hàn. Lórí títẹ́ Ẹ lọ́rùn. Lórí títan ìmọ́lẹ̀ fún Ìjọba Rẹ̀. Ní ìgbà tí ìfẹ́ Ọlọ́run bá jẹ́ àpẹẹrẹ ọ̀nà tí ò n gbà fẹ́ràn olólùfẹ́ rẹ, dípò jíjẹ́ kí àwọn ìṣe olólùfẹ́ rẹ jẹ́ àpẹẹrẹ ọ̀nà láti fẹ́ràn rẹ, ìgbéyàwó rẹ yíò jẹ́ èyí tí ó ní arinrin.
Ìwé mímọ́
Nípa Ìpèsè yìí

Ǹjẹ́ o nílò ohun tí yíò mú kí ìgbéyàwó rẹ sunwọ̀n sí i? Ẹ ka Ìwé Mímọ́, kí ẹ sì bá ara yín jíròrò fún ọjọ́ mọ́kànlélọ́gbọ̀n gbáko, ẹ ó sì rí bí Jésù yíò ṣe fi ara hàn yín!
More