Ètò Ọlọ́jọ́ Mọ́kànlélọ́gbọ̀n fún Àtúntò ÌgbéyàwóÀpẹrẹ

Tí o bá rò pé olólùfẹ́ rẹ ni ìṣòro rẹ tí ó tóbi jùlọ, lọ wo ara rẹ nínú dígí.
•••
Olólùfẹ́ rẹ kìí ṣe ìṣòro rẹ tí ó tóbi jùlọ. Ohùn yẹn lè sọ fún ọ pé òun ni. Tàbí ohùn yẹn lè sọ kẹ́lẹ́ kẹ́lẹ́ sí ọ ní etí pé ìwọ yíò ní ayọ̀ tí o bá ní olólùfẹ́ míràn tàbí pé kí o kúkú dá wà ni ó dára jùlọ. Tàbí ohùn kẹ́lẹ́ kẹ́lẹ́ yìí lè sọ fún ọ pé ipò tí o wà yìí gbá ọ́ láyè láti d'ẹ́ṣẹ̀. Má ṣe tan ara rẹ jẹ. Sọ fún Ọlọ̀run kí ó mú èrò ọkàn rẹ wà ní ìbámu pẹ̀lú àwọn Ọ̀rọ̀ Rẹ̀ àti ìdí tí ìgbéyàwó re fi wáyé. Sọ fún Sátánì kí ó kọjá lọ sí ibùgbé rẹ̀ ní ọ̀run àpáàdì ki ó sì sọ ìyè sí orí ìgbéyàwó rẹ. Sọ fún un pé kò sí ààyè fún un ní àyíká rẹ, o kò sì gbà á ní ààyè nínú ìgbéyàwó rẹ. Sọ fún un pé kí ó jáde kúrò ní ilé rẹ kí ó sì padà sí ibùgbé tìrẹ.
Ìwé mímọ́
Nípa Ìpèsè yìí

Ǹjẹ́ o nílò ohun tí yíò mú kí ìgbéyàwó rẹ sunwọ̀n sí i? Ẹ ka Ìwé Mímọ́, kí ẹ sì bá ara yín jíròrò fún ọjọ́ mọ́kànlélọ́gbọ̀n gbáko, ẹ ó sì rí bí Jésù yíò ṣe fi ara hàn yín!
More