Ètò Ọlọ́jọ́ Mọ́kànlélọ́gbọ̀n fún Àtúntò ÌgbéyàwóÀpẹrẹ

31 Day Marriage Reset

Ọjọ́ 16 nínú 31

Irú ìgbéyàwó tí ó dára jùlọ ní irú èyí tí àwọn ìbásepọ̀ àná tí ó pinni lẹ́mí kò ní ipá lórí bí òní ṣe rí.

•••

Ní ọ̀pọ̀lọpọ̀ àwọn àkókò, mó ní láti rán ara mi létí láti “yan àwọn ogun mi”. Mo máa ń sọ ọ́ ninu ọkàn mi ní ìgbà gbogbo tí Sátánì tàbí pàápàá jùlọ tí ẹran ara mi bá ń dà mí láàmú nípa nkan tí ó ṣẹlẹ̀ ní àná tàbí ní àwọn oṣù díẹ̀ sẹ́yìn. Ní ìgbà míràn yíò rí bíi pé kí n s'ọ̀rọ̀ nípa ohun tí ó ti kọjá lọ, ṣùgbọ́n eléyìí kò tọ̀nà. Kìí ṣe nítorí pé ó mú ìnira bá ìgbéyàwó mi nìkan ṣùgbọ́n pàápàá nítorí Ọlọ́run kò ṣe bẹ́ẹ̀ sí wa. Ohun míràn tí mo máa n béèrè lọ́wọ́ ara mi lemọ́ lemọ́ ni pé “ṣé ó tọ̀nà?” Ṣé ohun tí ó tọ́ ni láti sọ àkókò tàbí pàápàá ọjọ́ di ìbànújẹ́ nítorí mo ṣì ń ronú nípa ìgbà tí___________? Rárá, kò yẹ bẹ̀ẹ́. Èyí jẹ́ ọ̀kan nínú àwọn àkókò wọ̀nyẹn láti fi gbogbo rẹ̀ jì kí n sì jẹ́ kí Ọlọ́run ṣe iṣẹ́ ọwọ́ Rẹ̀. Èyí jẹ́ ọ̀kan nínú àwọn àkókò láti béèrè l'ọ́wọ́ Ọlọ́run fún ìrànlọ́wọ́ láti mú èrò náà kúrò nínú ọkàn mi, kí n sì fi gbogbo ẹwà àti ìbùkún tí mo ní pẹ̀lú olólùfẹ̀ mi ṣe àfojúsùn. Èyí ni ọ̀kan nínú àwọn àkókò láti lo àṣẹ mi lórí Sátánì làti yàgò fún mi ní orúkọ Jésù. Èyí jẹ́ àǹfààní làti rán an létí pé kò ní ní ipá nínú ìgbéyàwó mi. Má ṣe lo ohun tí ó ti kọjá gẹ́gẹ́ bíi ohun ìjà, fi sílẹ̀ ní ibi tí ó wà, gẹ́gẹ́ bíi ohun tí ó ti kọjá lọ. Dúpẹ́ l'ọ́wọ́ Ọlọ́run fún òní, sì jẹ́ kí olólùfẹ́ rẹ mọ̀ wípé inú rẹ dùn láti lò ó pẹ̀lú rẹ̀.

Ìwé mímọ́

Nípa Ìpèsè yìí

31 Day Marriage Reset

Ǹjẹ́ o nílò ohun tí yíò mú kí ìgbéyàwó rẹ sunwọ̀n sí i? Ẹ ka Ìwé Mímọ́, kí ẹ sì bá ara yín jíròrò fún ọjọ́ mọ́kànlélọ́gbọ̀n gbáko, ẹ ó sì rí bí Jésù yíò ṣe fi ara hàn yín!

More

A fẹ́ dúpẹ́ lọ́wọ́ ìjọ Stonecreek fún ìpèsè ètò yìí. Fún àlàyé síwájú síi, jọ̀wọ́ lọ sí: http://www.stonecreek.church