Bàbá Fẹ́ràn Rẹ láti ọwọ́ Pete BriscoeÀpẹrẹ

The Father Loves You by Pete Briscoe

Ọjọ́ 9 nínú 16

Ọjọ́ Kẹ̀sán

Ẹ̀bùn rere nípa ti oore ọ̀fẹ́

Máse dá mi lẹ́ jọ́. Mo ní owó pú pọ̀ —Samantha Bee

Wọ́n má hún dá wa lẹ́ jọ́ nígbà gbogbo ní ilé ayé yíì ní ipaṣẹ iṣẹ́ wá, ìrísí, àti àwọn ohun ìní. Bó ti lẹ̀ jẹ́ pé a kò sọ́ rárá ní ọ̀nà tó tọ́, oun tí o le jẹ́ ní ayé rẹ dá lórí nkan wọ̀nyí. Láìsí wọn, ìwọ kò jẹ́ nkankan.

Ṣùgbọ́n Ọlọ́run kò báwo se ní irú ọ̀nà bẹ́ẹ̀. Nítorípé Ó jẹ ní ìfẹ́, bí ó ṣe tẹ́wọ́ gbá wá dá lóri nkan tí ó yàtọ̀ pátápátá:

Nígbà náà ni Olúwa sọ̀kalẹ̀ nínú ìkùukùu, ó sì dúró níbẹ̀ pẹ̀lú rẹ̀, ó sì kéde orúkọ rẹ̀, OLúWA. Ó sì kọjá níwájú Mósè, ó sì ń kéde pé, “OLúWA OLúWA, OLúWA, aláàánú àti Ọlọ́run olóore-ọ̀fẹ́, Ó lọra láti bínú, ó sì pọ̀ sí i. ìfẹ́ àti ìṣòtítọ́, tí ń pa ìfẹ́ mọ́ fún ẹgbẹẹgbẹ̀rún, àti dídáríji ìwà búburú, ìṣọ̀tẹ̀ àti ẹ̀ṣẹ̀.” ( Ẹ́kísódù 34:5-7)

Ó jẹ́ ẹnì olóore ọ̀fẹ́.

Òun ni Ọlọ́run tí a pè ní “Bàbá.” Oore ọ̀fẹ́ rẹ̀ yí àwọn òfin padà lórí ohun gbogbo. Ó fi gbogbo agbára Rẹ̀ lé wa lọ́wọ́ bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé a kò ṣe nǹkankan láti tọ́ sí i.

Nítorípé nípa ore ọ̀fẹ́ ni o fi di ẹni tí a gbàlà, nípa igbagbọ́-àti pé èyí kì iṣẹ́ ti ara rẹ, ẹ̀bùn láti ọ̀dọ̀ Ọlọ́run ni, kì ṣe nípa iṣẹ́, kí ẹnikẹ́ni kí ó má ṣe gba ògo lórí rẹ̀. ( Efesu 2:8-9)

Kíni o le sọ sí ìyẹn? Báwo ni a ṣe dáhùn sí irú ìfẹ́?

Ọlọ́run, a dúpẹ́ lọ́wọ́ rẹ púpọ̀ fún bí o ṣe dì wá mú ní òdìwọ̀n tó yàtọ̀ si àgbáyé lọ. Fún ítú sílẹ̀ mi lọ́wọ́ àwọn ìrètí ìyípadà ní gbà gbogbo tí kò ṣeé ṣe jẹ́ ìtúsílè. Ràn mí lọ́wọ́ láti dojú kọ ẹ̀bùn Rẹ, ìgbàlà tí Èmi kò lẹ jogún, àti rí oun tí ó tọ́ nínú ìyẹn ju ohunkóhun mìíràn lọ! Àmín.

Ìwé mímọ́

Nípa Ìpèsè yìí

The Father Loves You by Pete Briscoe

A ti kọ́ wa láti kékeré pé Ọlọ́run ni Bàbá wa àti pé àwa jẹ́ ọmọ Rẹ̀. Ṣùgbọ́n níní ìbátan pẹ̀lú Ọlọ́run gẹ́gẹ́ bí Bàbá kì í rọrùn nígbà gbogbo—àgàgà bí àwọn bàbá wa ti orí ilẹ̀ ayé bá ń sapá láti fi ìfẹ́ tí a ń fẹ́ hàn wá. Nínú ìkẹ́kọ̀ọ́ ọlọ́jọ́ mẹ́rìndínlógún yìí, Pete Briscoe fa àfiyèṣí wa ṣọ́dọ̀ Ọlọ́run tó ń tẹ́ gbogbo àwọn èròngbà ìfẹ́ lọ́rùn—ó ń fi hàn bí Ìwé Mímọ́ ṣe fi hàn pé ó jẹ́ Bàbá wa rere àti Bàbá wa pípé.

More

A fẹ́ dúpẹ́ l'ọ́wọ́ Pete Briscoe fún ìpèsè ètò yìí. Fún àlàyé díẹ̀ si, jọ̀wọ́ lọ sí: http://petebriscoe.org/