Bàbá Fẹ́ràn Rẹ láti ọwọ́ Pete BriscoeÀpẹrẹ

Ọjọ́ Kẹjọ
Ìyọ́nú Àtọkànwá
Mo yan oore... Èmi yí ò ṣe ore sí àwọn tálákà, nítorípé wọ́n dá wà. Màá Ṣàánú fún ọlọ́rọ̀, nítorí ẹ̀rù ń bà wọ́n. Àti inú rere sí àwọn aláìṣòótọ́, nítorí irú èyí ni ohun tí Ọlọ́run ṣe sí mi. —Max Lucado
Mo fẹ́ràn àwọn ọ̀rọ̀ tí ó sọ nípa bí Ọlọ́run ṣẹ jẹ́ aláàánú.
"…nítorí olóore-ọ̀fẹ́ ni OLUWA Ọlọrun yín ó sì ní ìyọ́nú. Òun kì yóò yí ojú Rẹ̀ padà kúrò lọ́dọ̀ yin bí ẹ̀yin bá padà sọ́dọ̀ rẹ̀.” ( 2 Kíróníkà 30:9)
"Olúwa, Olúwa, aláàánú…” (Eksodu 34:6)
Àwọn ẹsẹ Bíbélì báyìi fihàn pé Ọlọ́run Bàbá wa kún fún àánú fún wa. Ó ṣe àbójútó gidi gan fún wa àti pé Ó ní ìmọ̀lára àbójútó yìí sí ìwọ àti èmi.
Èyí jẹ́ èrò tí ó jìn, tí o bá ronú nípa rẹ... Ìyọ́nú ó túmọ̀ sí “pẹ̀lú ìtara,”—ṣùgbọ́n gbé ìtumọ̀ àwọn ọ̀rọ̀ mẹ́ta wọ̀nyí yẹ̀wò: Ọlọ́run. Àánú. Ìwọ.Bàbá rẹ ọ̀run kì í ṣe ẹ̀rọ nínú ìfẹ́ Rẹ̀ sí ọ;Ó ní ìmọ̀lára rẹ̀.
Mo wà ní Philippines pẹ̀lu ẹgbẹ́ tí ó ńjíyìnrere kan l'àkókò kọ́lẹ́ẹ̀jì.. Ní abúlé kan, a bá ọmọkùnrin kan tó ní àrùn ẹ̀tẹ̀. Gbogbo èèyàn ló yàgò fún un—kò ṣeé fọwọ́ kàn án. Ṣùgbọ́n pásítọ̀ olóore ọ̀fẹ́ ti ṣọ́ọ̀ṣì ajíhìnrere kékeré tó wà nílùú náà na ọwọ́ rẹ̀. Òun nìkan ló múra tán láti gbá ojú, ọwọ́, àti ẹsẹ̀ ọmọkùnrin náà mọ́ra
Ṣùgbọ́n èmi kìí yóò gbàgbé òwúrọ̀ tí mo wà ní igun kan tí mo sì rí ọmọkùnrin kékeré yìí jókòó ní orí itan ti ọ̀kan nínú àwọn ẹlẹgbẹ́ mi, Randy. Randy ti kọ́ ọ bí ó ṣe lè ṣeré "Patty-cake".Bí àwọn ọwọ́ Randy ṣe ńkan àwọn kùkùté ọmọkùnrin náà, ojú rẹ bú sínú ẹ̀rín láti inú ọkàn rẹ̀ wá, àti pé mo ríi àwòrán tí ó hàn gbangba ti àánú Ọlọ́run—ṣùgbọ́n pẹ̀lú ìwòye nlá kan… Èmi ni ọmọkùnrin tí ó jókòó ní itan Bàbá mi Ọlọ́run.
Bàbá, fífi Ọmọ Rẹ ránṣẹ́ láti jìyà fún mi ni ìrísí àánú tí ó ga jùlọ! Jẹ́ kí n rí ara mi gẹ́gẹ́ bí ọmọ adẹ́tẹ̀ lórí itan Rẹ. O ṣeun fún ìfẹ́ mi pẹ̀lú ìtara tí ó jẹ́ pé Ìwọ nìkan ni O le ṣaájò bẹ́ẹ̀, fún fífẹ́ mi sí pípé. Jọ̀wọ́ ràn mí lọ́wọ́ láti rí ayé nípasẹ̀ bí O ṣe ríi kí èmi tún lè fi àánú Rẹ hàn sí ayé! Amin.
Ìwé mímọ́
Nípa Ìpèsè yìí

A ti kọ́ wa láti kékeré pé Ọlọ́run ni Bàbá wa àti pé àwa jẹ́ ọmọ Rẹ̀. Ṣùgbọ́n níní ìbátan pẹ̀lú Ọlọ́run gẹ́gẹ́ bí Bàbá kì í rọrùn nígbà gbogbo—àgàgà bí àwọn bàbá wa ti orí ilẹ̀ ayé bá ń sapá láti fi ìfẹ́ tí a ń fẹ́ hàn wá. Nínú ìkẹ́kọ̀ọ́ ọlọ́jọ́ mẹ́rìndínlógún yìí, Pete Briscoe fa àfiyèṣí wa ṣọ́dọ̀ Ọlọ́run tó ń tẹ́ gbogbo àwọn èròngbà ìfẹ́ lọ́rùn—ó ń fi hàn bí Ìwé Mímọ́ ṣe fi hàn pé ó jẹ́ Bàbá wa rere àti Bàbá wa pípé.
More